PDP: Ìgbésẹ̀ iléeṣé aàrẹ farapẹ́ 'ìdìtẹ̀ gbàjọba'

Muhammadu Buhari, aarẹ̀ orilẹede Naijiria Image copyright Presidency Nigeria
Àkọlé àwòrán PDP ni ami iditẹ gbajọba alagbada ni awọn alagbara kan nileeṣẹ aarẹ n rawọ le

Ẹgbẹ oṣelu PDP ti n fi ẹsun kan ileeṣẹ aarẹ lorilẹede Naijiria pe awọn alagbara kan nibẹ ti pari eto gbogbo lati pe ẹjọ lori boya Sẹnetọ Bukọla Saraki ṣi lẹtọ lati di ipo aarẹ ile aṣofin agba mu.

Ninu atẹjade kan, alukoro fun ẹgbẹ oṣelu PDP, Kọla Ologbodiyan fẹsun kan ẹgbẹ oselu APC pẹlu pe o fẹ gba ọna alumọkọrọyi yẹ aga aarẹ ile aṣofin agba mọ Saraki nidi.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni ami iditẹ gbajọba ti alagbada ni awọn alagbara kan nileeṣẹ aarẹ n rawọ le eleyi to ni awọn yoo fi ohun yoo wu to ba gba ko loju.

Amọṣa, ileeṣẹ aarẹ ni ko si ohun to kan ileeṣẹ aarẹ pẹlu iwa ti ko bofinmu nitori ijọba to bọwọ fun ofin ni ijọba aarẹ Muhammadu Buhari ati pe igbakeji aarẹ to n dele gẹgẹ bii aarẹ bayii ko lee lọwọ ninu irufẹ iwa bẹẹ.