Ọ̀ṣọ́ Aṣọ Òkè ti kọjá lílo ìlẹ̀kẹ̀ níkan
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Yinka Oke: Àrà tuntun tí aṣọ òkè Yorùbá ń gbé jáde ti di àwò-dami-ẹnu

Aṣọ òkè gbàràdá, ó di ọmọ tuntun ti gbogbo ayé ń pé wò lọ́jà.

Abilekọ Yinka Adesanya Oke tó jẹ akọṣẹmọṣẹ lórí ṣiṣẹ ọ̀ṣọ́ si àṣọ oke ba BBC Yorùbá sọ̀rọ̀ lori ọmọ ti ayé bí ti ayé ń pọ̀n bayii nibi ẹ̀ṣọ́ ṣiṣe si ara aṣọ oke Yoruba.

Aṣọ oke Yoruba gbayii ni ode ọmọluwabi gbogbo bii igbeyawo, ikomọjade, ifinijoye, iṣile àti bẹẹ bẹẹ lọ.

Laye atijọ, ìró àti bùbá ni fun obinrin ṣugbon bayii, igba ti yipada, Yinka Oke sọrọ lori àwọn àrà oniruuru ti àwọn eniyan n fi aṣọ oke da lasiko yii.

Bi o ṣe jẹ́ akẹkọọ oye ọmọwe (Ph.D) ni fasiti Eko naa lo tun jẹ òntajà aṣọ òkè tó ń ṣe é lọ̀ṣọ̀ọ́ ní onírúurú ọ̀nà tí oníbarà bá fẹ́ lati fi gbe ogidi àṣà Yoruba ga.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ sí: