Serena Williams: Mọ̀ sínú, mọ̀ síkùn ni ìdí tí mo fi kọ̀

Serena Williams Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Williams to pada si ni gbabọọlu ẹlẹyin lẹyin ti o bi ọmọbinrin rẹ, fi idi rẹmi nigba to n figagbaga pẹlu Briton Johanna Konta pẹlu ami ayo 6-1 6-0.

Ilumọọka agbabọọlu ẹlẹyin, Serena Williams, ti fi lede pe oun ko ni kopa ninu Idije Ife Ẹyẹ Rogers Cup ti yoo waye ni Canada ni ọsẹ to n bọ.

Serena Williams to jẹ ẹni to gbe igba oroke julo ninu awọn to n gba bọọlu ẹlẹyin sọ pe, oun kò lè sọ idi ti oun ko fi ni kopa ninu idije naa fun ẹlomii rara.

O ni ọdọ oun nikun wa, ko ni hande si ẹnikẹni.

Williams to pada si ni gbabọọlu ẹlẹyin lẹyin ti o bi ọmọbinrin rẹ, fi idi rẹmi nigba to n figagbaga pẹlu Briton Johanna Konta pẹlu ami ayo 6-1 6-0.

Image copyright Getty Images

Adari eto Idije Ife Ẹyẹ Rogers Cup, Eugene Lapierre, ni ko dun mọ awọn ninu bii Serena Williams se yẹra kuro ninu idije naa, amọ O wi pe ọpọlọpọ awọn ilumọọka agbabọọlu ẹlẹyin ni yoo kopa ninu idije naa ti yoo bẹrẹ ni ọsẹ to n bo ni Canada.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionỌdunlade Adekọla gbóṣùbà fáwọn ọkùnrin tó ń ran ìyàwó wọn lọ́wọ́
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Obìnrin tí kó ba fẹ́ òṣìṣẹ́ Mọ́ṣúárì, ìpinu rẹ̀ mẹ́hẹ'
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFẹla Durotoye: ọ̀rọ̀ ìṣọ̀kan Nàìjíríà tó àpérò ọmọ eríwo

Related Topics