Fadele: Dán an wò, lóbí ìyá ọ̀kẹ́rẹ́ ni a fi ọ̀rọ̀ ọ̀kadà náà ṣe

Fadele: Dán an wò, lóbí ìyá ọ̀kẹ́rẹ́ ni a fi ọ̀rọ̀ ọ̀kadà náà ṣe

Àwa kìí ṣe wèrè, ìpinnu wa ni láti ṣe ńkan tuntun ní ọ̀nà tuntun- Fadele

Fadele Adu ọkan lara awọn akọni mẹrin naa ṣalaye fun BBC Yoruba pe oun kọ lo kọkọ ṣe eyi ri.

O ni ẹgbon oun, Tunde ati ọrẹ rẹ kan lo kọkọ rin irinajo ọlokada yii wa si Naijiria lọdun melo sẹyin ni èyí tó wa jẹ́ ìwúrí fún òun atawọn to ku.

Bakan naa ni Tunde sọrọ lori ìrírí to kọja ẹgbẹ́ abewú nìgbà akọkọ to gbe mọto wa sile lati Germany ti oun gba Turkey lọ si Niger si Sahara Desert si Kwara ko to dele ni Ondo.

Fadele rọ gbogbo ènìyàn láti bẹ̀rẹ̀ igbesẹ lori ohunkohun to wu wọn lati ṣe si daadaa nitori kò si ohun tuntun labẹ ọ̀run mọ́.

Ati pe kò sí nkan ti kò ṣeeṣe ti o ba ti ni àfokansi ati ipinnu rere.

Àrà meriiri ni ki àwọn eniyan pinnu lati ṣe nkan to wu wọn bii ọkada gigun lati ilẹ̀ kan si ikeji laarin ọpọlọpọ orilẹ-ede.

Ajanaku kọja mo ri nkan fìrí ni ohun ti àwọn akọni mẹrin yii ṣe. Bi a ba ri erin, ki a gbà pẹ a ri erin.

Fadele rọ àwọn ọ̀dọ́ Naijiria lati pinnu nkan rere fun ẹ̀kọ́ ọjọ ola wọn.