Sunday Ayẹni: Damilọla, aya ọmọ mi fìgbónára sọ mi sókùnkùn alẹ́

Sunday Ayẹni: Damilọla, aya ọmọ mi fìgbónára sọ mi sókùnkùn alẹ́

Ibanujẹ nla ni ki majesin toju òbí rẹ̀ rọ̀run!

Sunday Ayẹni, baba oloogbe sọ fun BBC Yoruba pé 'Ọjọ buruku eṣu gbomi mu ni ọjọ́ Ẹti to gbọ iroyin pe Damilọla aya ọmọ rẹ ti gun Olumide pa'.

O ṣalaye pe àwọn mejeeji ti maa n ja fún ọpọlọpọ igba lataari igbonara Damilọla iyawo rẹ to jẹ ọmọ ọdun mẹtalelogun.

Wọn bimọ meji funra wọn ninu igbeyawo ọdun meji.

O mẹnuba awọn igbesẹ ti oun ti gbe lati fi ya igbeyawo naa ṣugbọn ti obi Damilọla n bẹbẹ pe wọn ko mọ ibi to ti kọ iwakiwa yii.

Ireti baba Olumide Ayẹni ni pe ki Olorun ati ijọba ṣe idajọ ọrọ yii bo ti yẹ.

Ọrọ ki ololufẹ maa fibinu gun ara wọn pa ti to apero ọmọ eriwo ni Naijiria bayii.

Iwa ipá ninu idile ti n bi ige ati Adubi ti ko faaye gba alaafia ninu igbeyawo mọ ni eyi ti awọn onimọ ti gba lọkọlaya lati tubọ ni suuru tabi ki wọn yẹra funra wọn ti ọrọ kò ba wọ mọ.