'Daura' di orúkọ tó ń bí awuyewuye lóríṣiríṣi ní ayélujára

Ọsinbajo ati Daura
Àkọlé àwòrán Lati igba ti Lawal Daura ti bẹrẹ iṣẹ ni awuyewuye loriṣiriṣi ti n jẹyọ lori ihuwasi rẹ.

Iroyin to n tẹ wa lọwọ ti sọ pe ọga agba ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS, Lawal Daura, ti adele Aarẹ, Yemi Osinbajo yọ nipo ti kuro lahamọ bayii.

Iroyin naa tun sọ pe Daura ko ni lanfani lati rinrin àjò lọ silẹ okeere lẹyin ti wọn ti gba iwe irinna rẹ bayii.

Adele Aarẹ Osinbajo yọ Daura nipo lẹyin to ran ọtẹlẹmuyẹ DSS lati dina mọ awọn aṣofin agba ti wọn fẹ wọle l'Abuja.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Iyansipo Lawal Daura gẹgẹ bi ọga agba ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS lọdun 2015, mu awuyewuye dani.

Ọpọlọpọ ọmọ Naijiria lo fi oju aitọ wo o, nitori pe ipinlẹ Katsina l'oun ati Aarẹ Muhammadu Buhari ti jọ wa, ati lori 'aikoju oṣuwọn rẹ fun iṣẹ naa'.

Bakan naa lo jẹ wi pe Daura ti fẹhinti kuro lẹnu iṣẹ nileeṣẹ ajọ DSS, ko to di pe Buhari tun pe e pada. O tun jẹ ọkan lara ọmọ igbimọ fun eto aabo ati ọtẹlẹmuyẹ fun ẹgbẹ oṣelu APC lasiko eto idibo ọdun 2015.

Lati igba to si ti bẹrẹ iṣẹ ni awuyewuye loriṣiriṣi ti n jẹyọ lori ihuwasi rẹ.

O tako iyansipo alaga ajọ EFCC

Daura tun kọ iwe ẹsun si ile aṣofin nipa ọga agba ajọ EFCC, Ibrahim Magu, eyi to mu ki awọn 'koju oro si iyansipo rẹ.'

Eto igbanisiṣẹ ajọ DSS

Awuyewuye jẹyọ lori eto igbanisiṣẹ awọn oṣiṣẹ ọrinlenirinwo din ẹyọ kan, 479, tuntun fun ajọ DSS.

Ninu 479 ni ipinlẹ Katsina ti ni eniyan mọkanlelaadọta, 51, eyi to ju ida mẹwa gbogbo awọn ti wọn gba siṣẹ jake-jado Naijiria lọ.

Ọpọlọpọ lo bu ẹnu ẹtẹ lu Daura nigba naa pe bawo ni ipinlẹ Katsina, to jẹ ipinlẹ rẹ yoo ṣe ni to bẹ ju awọn ipinlẹ yooku lọ.

Oun ati ajọ EFCC naa jọ woju ara wọn.

Wọn fi ẹsun kan iṣakoso rẹ fun obitibiti biliọnu Naira ti wọn fi kọ ile ẹkọ DSS ni ipinlẹ Katsina; kikuna lati jẹ ki olubadamọran lori eto aabo Naijiria nigba kan, Sambo Dasuki, wa sile ẹjọ lati jẹri lori awọn ẹsun to ni i ṣe pẹlu iwabajẹ.

Ni ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kọkanla, ajọ DSS da awọn oṣiṣẹ ajọ EFFC duro lati maa fi ofin gbe Ita Ekpeyong, to jẹ Ọga agba ajọ DSS tẹlẹ, lai fi ti pe wọn ni aṣẹ lati mu u ṣe.

Image copyright Twitter
Àkọlé àwòrán Ọjọ́ keje, oṣù Kẹjọ ni Adele Aarẹ, Yẹmi Ọsinbajo gba iṣẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀

Bakan naa ni wọn ni ko jẹ ki wọn o fi ofin gbe Ọga agba ajọ ọtẹlẹmuyẹ ti National Intelligence Agency, NIA, Ayodele Oke, ti Aarẹ Buhari da duro lẹnu iṣẹ.

Ẹsun kikowo ilu jẹ ni ajọ EFCC n wa ọga agba DSS ọhun fun.

Wọn ko awọn oṣiṣẹ alaabo kuro lọdọ awọn aṣofin

Ninu oṣu Kẹfa, 2018, ariyanjiyan kan tun waye lori bi wọn ṣe n pin awọn oṣiṣẹ alaabo fun awọn to di ipo oṣelu mu, eyi to mu ki ajọ DSS ko ida marundinlọgọta awọn oṣiṣẹ alaabo kuro lọdọ awọn awọn olori ile aṣofin.

Lara awọn ti ọrọ naa kan ni Bukọla Saraki, Yakubu Dogara, Ike Ekweremadu ati Lasun Yusuf.

Lẹyin awuyewuye yii ni ajọ DSS da diẹ lara awọn oṣiṣẹ eleto aabo Saraki ati Dogara pada fun wọn, lẹyin ipade kan to da lori eto aabo ti Igbakeji Aarẹ, Yemi Ọsinbajo ṣe pẹlu awọn mejeeji.

Awọn iroyin kan sọ pe wahala naa waye nitori pe ile aṣofin kọ aba kan tileeṣẹ aarẹ buwọlu lati fi owo kun owo fun ajọ DSS ninu owo iṣuna 2018.

Eyi to kadi rẹ nilẹ ni ti bi awọn oṣiṣẹ ajọ naa ṣe di ẹnu ọna ile aṣofin lọjọ Aje, ọjọ keje, oṣu Kẹjọ.

Mathew Seiyefa ni Ọsinbajo yan lati ma de ile gẹgẹ bi ọga ile isẹ ọtẹlẹmuyẹ lorileede Naijiria.

Idaduro Daura ko sẹyin bi awọn ọmọ ile isẹ ọtẹlẹmuyẹ se dina wiwọle mọ awọn asofin agba l'owurọ ọjọ Iṣẹgun.

Ko ti daju ibi ti Lawal Musa Daura wa bayi sugbọn iroyin kan so wi pe ọkọ re to gbe wa si ile ijọba ko lo gbe pada kuro nibe nigba ti wọn wa jade.

Kini Awọn eeyan n sọ nipa idaduro Daura

Loju opo Twitter iriwisi otọọtọ ni igbesẹ naa mu wa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÌgbésí ayé àwọn ọmọdébìnrin wọ̀nyìí di ọ̀tun láti 2008