Sagay: olùdámọ̀ràn Buhari wọ gàu lórí ọ̀rọ̀ Adeosun

ọ̀jọ̀gbọ́n Itse Sagay Image copyright Twitter/Sagay
Àkọlé àwòrán Àwọn èèyàn sí ọ̀jọ̀gbọ́n Itse Sagay sọ lórí ẹ̀sùn ìwé ẹ̀rí mínísítà ètò ìnánwó Kemi Adeosun

Ọpọ eeya lo ti bu ẹnu atẹ lu bi Itse Sagay to jẹ oludamọran pataki fun Aarẹ Muhammadu Buhari lori igbogu ti iwa ibajẹ ṣe sọ pe ki minisita fun eto inanwo maa ṣe fipo rẹ silẹ koda to ba jẹbi ẹsun ti wọn fi kan pe ko ni iwe ẹri agunbanirọ nigba ti o sọ fun Aarẹ ile Asofin Agba l'Abuja Bukola Saraki pe ko kọwe fipo silẹ.

Oju opo twitter kun fun ọrọ malegbagbe ti awọn eeyan sọ lori ọro ti oludamọran Aarẹ naa sọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Reno Omokri loju opo Twitter tiẹ sọ pe o ṣẹṣẹ han gbangba idi ti Ọjọgbọn Sagay fi n satilẹyin fun Aarẹ Buhari.

O sọ pe iwe ẹri ko ni itumọ sii nitori wipe o ṣegbe lẹyin Aarẹ Buhari

Kayode Ogundamisi loju opo tiẹ sọ pe o ṣeni laanu wipe iru ojọgbọn bi Sagay lo sọ iru ọrọ bayii lẹyin iṣẹ to ti ṣe fun itẹsiwaju eto idajọ lorilẹede Naijiria.

Jeff Okoroaffor sọ pe o yẹ ki Ọjọgbọn Itse Sagay gẹgẹ bi oludamọran pataki fun Aarẹ Muhammadu Buhari kọwe fipo silẹ ni.

O fi kun ọrọ pe Sagay ko yẹ lati maa dari ọfisi ajọ to ri si igbogun ti iwa ajẹbanu lorilẹede Naijiria.