Ronkẹ Oṣodi: Mo kórira ki aya má ni ìtẹríba fún ọkọ nínú ilé

Ronkẹ Oṣodi: Mo kórira ki aya má ni ìtẹríba fún ọkọ nínú ilé

'òótọ́ ọ̀rọ̀ máa ń korò gan ni f'áwa èèyàn'

Gbajugbaja oṣere Yollywood, Ronke Oṣodi Oke ba BBC sọrọ lori pataki ki lọkọ laya bọwọ fun ara wọn.

O tun sọrọ lori ede-aiyede aarin oun ati Liz Anjọọrin to jẹ oṣere Yorùbá pe ti inu wọn ba rọ tan, ohun gbogbo a yanju fun onikaluku.

Ronke mẹnuba iṣẹ awọn sọrọ-sọrọ loju agbo ode inawo ni Naijiria pe: Gbogbo MC Nàìjíríà ló n ṣagbe lọna kan tabi omiran.

O mẹnuba awọn ọrọ rẹ kọokan ti awọn eniyan ti fun ni itumọ mii ti wọn si ti fi pa oun lẹkun sẹyin.

Bakan naa lo ni ọkan oun da oun láre pé oun ko ṣe Liz Anjọrin rara. Pe nigba to ba ya, gbogbo ọrọ naa a yé onikaluku.