Ọ̀ṣun Oṣogbo 2018: Ulrich Salazar wálé ọdún láti New York

Ọ̀ṣun Oṣogbo 2018: Ulrich Salazar wálé ọdún láti New York

Arugbá ti ṣetan láti gbé ìgbà fún ọdún 2018 kí àláàfìà lè jọba ní Ọṣun.

Oṣù kẹjọ ọdọọdun ni iran Yoruba maa n bọ odò Ọṣun ni ilu Oṣogbo ni ipinlẹ Ọṣun ni ẹkun iwọ oorun Naijiria.

Pataki ọdun yii ni lati fi gba adura si oriṣa Ọṣun ti itan gba pe o jẹ ọkan lara awọn aya Ṣango.

Ulrich Salazar, oyinbo kan lati New York ni orilẹ-ede Amẹrika wa lara àwọn alejo to ti de si Oṣogbo to jẹ olu ilu ipinlẹ Oṣun fọ́fọ́.

Ulrich ba BBC Yoruba sọrọ lori ìrírí rẹ̀ láti igba to ti de paapaa lori odo naa, ojubọ Obatala to ti de ati alaafia ati idunnu ti oun woye rẹ lara gbogbo awọn to ti de fun ọdun.