Yemi Osinbajo: Mo bá ìdílé tó pàdánù èèyàn wọn kẹ́dùn

ile to dawo
Àkọlé àwòrán,

Ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún to wáyé ni dédé ààgo méjìlá ọsán oni.

Àdelé ààré Ọ̀jọ̀gbọ́n Yemi Osinbajo tí kọ́wọ̀ rin pẹ̀lú àwọn èèkan nínú ijọba láti sàbẹ̀wò si ibi ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá ibi tó wáyé lọsàn oni lágbagbe Jabi l'Abuja nibi ti ile alájà marùn-ún ti wo ti àwọn ènìyan sì farapa.

Adele ààrẹ Yemi Osinbajo fi ìdínú rẹ̀ han lóri bi wọn ṣe ń gbìyànjú láti dóòlà ẹmi àwọn ènìyàn to ha sínú ile náà, o ni oun ní ìgbàgbọ pé gbogbo wọn ni yóò jáde láàyè.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé àwòrán,

Ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún to wáyé ni dédé ààgo méjìlá ọsán oni.

Awọn oṣìṣẹ́ FERMA sàla[yé peé ènìyàn mẹ́fa ni wọn ti ri yọ lọ́bẹ́ ilenáà nígbà ti àwọn osiṣe sì ń tẹ̀síwájú lati yọ àwọn míràn tó kù.

Ilé alájà márùn-ún tó já ní agbègbè Jabi ní'lú Abuja tí ṣe olúlùún orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni wọn ni ọ̀pọ̀ ènìyàn ti há sí abẹ rẹ̀.

Ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún to wáyé ni dédé ààgo méjìlá ọsán oni.

Ọgá àgba alábọjuto ìgboro Abuja Umar Shuaib tó ń ṣe agbátẹrun bí wọn ṣe ń doolà ẹ̀mí àwọn ènìyàn, kò tíì sí àrídájú iye ènìyàn tó wà lábẹ́ ilé náà tàbí àwọn ti wọn ti yọ jáde.

Àkọlé àwòrán,

Ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún to wáyé ni dédé ààgo méjìlá ọsán oni.

Ìròyìn to BBC lọ́wọ́ ní pe ènìyàn kan pàdánù ẹmi ẹ àwọn márùn-ún farapa nígbà ti àwọn miran ṣì wà lábẹ́ ilé náà.

Tẹ o bá gbàgbé láìpẹ́ yìí ní ọmọ ẹgbẹ́ akọ́lé (CORBON) àti àjọ tó ń mojú to bí ǹkan ṣe jé ojuú lówó sí (SON) ṣe ìpàdé láti fopin si ohuntó ń fa il'w tó n wó ni Nàìjíríà.

Àkọlé àwòrán,

Ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún to wáyé ni dédé ààgo méjìlá ọsán oni.