Ìdíje ọpọ́n ayò títa ni Ẹ̀gbá ń ṣí ojú àwọn ọ̀dọ́ Yorùbá si àṣà wa

Ìdíje ọpọ́n ayò títa ni Ẹ̀gbá ń ṣí ojú àwọn ọ̀dọ́ Yorùbá si àṣà wa

Alagba Laolu Laoshe lo ṣagbekalẹ idije

Alagba Lanre Laoshe lo ṣagbekalẹ idije ti Abẹokuta láti sọ àṣà naa jí.

Ọpọn ayò tita jẹ ọkan pataki lara eré ti awòn baba nla Yoruba maa n ta lati fi sinmi lẹyin iṣẹ́ oojọ wọn labẹ igi bii igi ọdán ni aarin abule.

Asiko yii ni wọn maa n ni anfani lati takurọsọ pẹlu àwàdà laarin ara wọn ti wọn ba n gbafẹfẹ ti wọn yoo si tun maa la awọn ọ̀dọ́ to wa nibẹ lọ́yẹ lori ìrírí ayẹ loriṣiiriṣii.

Kọ ọmọ rẹ ni àwọn eré idanilaraya iran Yoruba to n sọ ọpọlọ ọmọ di pipe sii paapaa lasiko isinmi yii.

Gbogbo àwọn tó kópa ninu idije ọpọn ayo tita nilu Abeokuta nipinlẹ Ogun ni Naijiria ni wọn lọ sile pelu ẹbun owo ti awọn oludije to gbegba oroke si ni ẹbun to pọ.

Wọn ṣeto yii lati fi ṣi oju awọn ọ̀dọ́ Yoruba si ọpọn ayo tita nitori pe oriṣa ti a ko ba fi idi rẹ han èwe kii pẹ parun.

Ẹ ma jẹ́ ki àwọn àṣà Yorùbá to ń gbe ìṣọ̀kàn sókè parun!

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: