Àràfá 2018: 100,000 òsìsẹ́ aláàbó ni Saudi lò fún ààbò tó péye

Awọn Alalaji

O le ni eeyan miliọnu meji jake-jado agbaye, to fi mọ awọn ọmọ Naijiria to to ẹgbẹrun lọna marundinlọgọta, ti wọn n gun oke Arafa lọjọ Aje, eyi to jẹ ohun to se pataki julọ ninu eto haji sise.

Lọjọ Aiku ni wọn bẹrẹ isẹ haji wọn nigba ti wọn pejọ silu Mina. bi oorun si ti yọ, lawọn omilẹgbẹ eeyan naa ti wọn da bii omi ninu asọ funfun, n gun oke Arafa yii, eyi to to kilomita mẹẹdogun si ila oorun ilu Mekkah, lẹyin ti wọn lo alẹ ọjọ kan lati sasaro ati ẹbẹ adura labẹ agọ ti wọn kọ fun wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Obìnrin akunlé ìgbàlódé

Lẹ́yin tawọn alarafa yii gbọ waasi tan ni mọsalasi Namira, ni wọn tun wa se adura Dhuhr ati Asr papọ ni ọna kukuru.

Awọn alarafa naa yoo lo akoko wọn loke Arafa yii lati gbadura fun itẹwọgba isẹ haji wọn ati kika ẹsẹ iwe mimọ Alukurani titi ti oorun yoo fi wọ.

Lẹyin ti oorun ba wọ, lawọn alarafa yii yoo morile Muzdalifah, to jẹ idaji irin laarin oke Arafa si ilu Mina, ti wọn yoo si duro di oru. Lẹyin ti wọn ba kirun Maghreb ati Isha papọ, ni wọn yoo wa bẹrẹ adura.

Gbogbo awọn alarafa yii, ni ọkọ bọọsi ti fẹẹ ko de si inu agọ ti wọn se fun wọn naa, nigba tawọn miran fẹsẹ rin.

Ijọba orilẹ-ede Saudi-Arabia ti wa pese awọn ohun eelo ati osisẹ to yẹ lati jẹki isẹ Haji naa lọ laisi wahala kan-kan, ko si tun yọri si rere.

Koda, eto aabo to gbopọn, pẹlu osisẹ agbofinro to to ẹgbẹrun lọna ọgọrun ni wọn mu lati oniruuru ẹka to wa labẹ ileesẹ eto abẹle, ti wọn si pin wọn si awọn ibudo awn alalaji naa kaakirifun ipese eto aabo to peye

Àkọlé àwòrán,

Ìléyá ti dé, èran ọdún di jíjẹ!

Ninu iroyin miran ẹwẹ, ijọba Ipinlẹ Eko ti fofin de iwa tita ẹran agbo l'awọn oju opopona kan nipinlẹ naa, nibayii ti bi ọdun ileya wọle de tan.

Nigbati o n ba awọn akọroyin sọrọ, Kọmisọna fun ọrọ ayika nipinlẹ Eko, Babatunde Durosinmi- Etti sọ pe, o ṣe pataki fun awọn ara ilu Eko lati tọju ayika wọn, bi wọn ṣe n yọ ayọ ọdun.

O fi kun ọrọ rẹ pe, ofin to de ọja tita loju popo naa lo de agbo tita loju popo nipinlẹ Eko.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Erelu Ọba Oṣunfunmike Ajike rèé tí wan tọrọ nídìí Ọṣun

Kọmisọna naa tun gba awọn ara ilu Eko ni imọran, lati palẹ idọti wọn ninu ọdun, ki ayika wọn le mọ tonitoni, papaa julọ ki wọn o le dena ajakalẹ-arun.

Ọjọ́ Iṣẹgun ati Ọjọru ni ìjọba Naijiria kéde fun ìsinmi.

Ẹwẹ, Abdulrahman Dambazu to jẹ minista fun ọrọ abẹlẹ ni Naijiria kede pe ko ni si iṣẹ ni ójọ kókanlelogun ati ọjọ kejilelogun, oṣu kẹjọ, ọdun 2018 fun sisami ọdun Ileya.

O rọ awọn ara ilu lati ṣe ọdun naa laisi wahala kankan ki wọn si lo asiko naa lati fifẹ han si ọmọnikeji wọn.

Ọdun ileya jẹ ọdun nla fun àwọn musulumi ododo kaakiri agbaye.

Àkọlé fídíò,

Ọ̀ṣun Oṣogbo 2018: Ulrich Salazar wálé ọdún láti New York

Àkọlé fídíò,

Irun gígẹ̀ kọjá orí fífá lásán

Àkọlé fídíò,

Ẹni ti ko riran to nlọ'ta ni Mushin

Àkọlé fídíò,

Wùnmí Toríọlá: Toyin Abraham kìí se ọ̀gá mi nínú tíátà