Kofi Annan: Àkàndá ìbejì to gbọ́ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ èdè, to tún fẹ́ ọmọ Yoruba níyàwó

Kofi Annan ati ọmọ rẹ Ama nigba to fẹ ọmọ Naijria

Oríṣun àwòrán, MODERNGHANA.COM

Àkọlé àwòrán,

Ọmọ ilu Eko ni akọbi Kofi Annan, Ama, fẹ

Akọ̀wé àpapọ̀ tẹ́lẹ̀ rí fún àjọ ìsọ̀kan agbayé (UN), Kofi Annan, to papoda ni ẹni ọgọrin ọdun kii ṣe eniyan lasan. Gbogbo ọrọ ẹ ku ara fẹraku ti awọn eeyan kakakiri agbaye ti n sọ nipa rẹ nikan kọ lo fi han pe eniyan ọtọ ni.

Taa ba si ka itan igbesi aye Annan yii, aa mọ pe ẹni ti Ọlọrun da nii se.

Awọn nkan ti ọpọlọpọ lee ma mọ nipa akọni ọkunrin Ghana yi pọ pupọ, ẹni to dele aye ni ọdun 1938, amọ diẹ ninu wọn ree.

Ohun to yẹ ko mọ nipa Kofi Annan:

  • Ọmọ Yoruba kan ti orukọ rẹ njẹ Titi Alakija, ni Annan kọkọ fẹ niyawo ni ọdun 1965. Ṣugbọn wọn pinya lẹyin bii ọdun mẹwaa. Wọn bi ọmọ meji - Ama ati Kojo.
  • Ibeji ni Kofi Anna jẹ; ekeji rẹ Efua Atta, ku ni ọdun 1991.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

  • Alahan goolu ni nitori pe o le sọ ọpọlọpọ ede. Anna le sọ ede Ilẹ Geesi ati Faranse daradara. Yat si ede abinibi rẹ ti a mọ si Akan, ti wọn n sọ ni orilẹede Ghana, o tun gbọ awọn ede Kru ti wọn n sọ ni awọn ẹya Ivory Coast ati Liberia. Yatọ si eyi, o tun le sọ awọn ede Afrika miran.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

  • Idile ọlọla Ashanti ati Fante ni wọn bii si ni orilẹede Gold Coast to di Ghana bayii.
  • O jẹ alaga igbimọ awọn agba agbaye (The Elders) eyi ti aarẹ South Africa nigba kan ri, Nelson Mandela gbe kalẹ.

Oríṣun àwòrán, Twitter

  • Igba to wa ni ọmọ ọdun merinlelogun lọdun 1962, lo darapọ mọ ajọ isọkan agbaye, UN, gẹgẹbi oṣiṣe ajọ agbaye to n ri si eto ilera (WHO).
  • Orukọ rẹ 'Kofi' tumọ si Ọjọ Ẹti ni ede Akan.
  • Ija ẹlẹyamẹya to ṣẹlẹ ni Rwanda wa lara awọn nkan ti o dun Kofi Annan titi to fi ku nitori pe, wọn ni ko gbe igbesẹ to to lati doola ẹmi awọn ara orilẹede naa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Kofi Annan ni o yẹ ki oun gbe igbeṣẹ ju eyi ti oun gbe nigba ija ẹlẹyamẹya Rwanda

  • Ọdun 2001 lo gba ami ẹyẹ Nobel Prize fun wiwa alaafia gbogbo agbaye. Wọn ni, o ṣiṣẹ takuntakun lati fopin si aarun kogboogun (HIV), igbesunmọmi kaakiri agbaye ati lati fopin si titẹ ẹtọ ọmọniyan loju mọ'lẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ami ẹyẹ Nobel Prize lo gba fun iṣẹ alaafia

Àkọlé fídíò,

Fídíò BBC yọ àwọn èèyàn FIFA níṣẹ́ ṣááju Russia 2018