Ogungbinle: Àwọn onílé rò pé asẹ́wó ni mi

Duru Azukbike
Àkọlé àwòrán,

Ìdàmú àwọn obìnrin tí kò tíì lọ́kọ pẹ̀lú ilé wíwá

Ọpọ onile lorilẹde Naijiria ni kii fẹ gba awọn obinrin ti kosi nile ọkọ sile, wọn maa n ro wipe aṣẹwo ni wọn.

Olufunmilọla Ogungbile, to niṣẹ gidi lọwọ ni, iru iriri bẹẹ ni ilu Abeokuta, nipinlẹ Ogun.

Ogungbile to jẹ ẹni ọgbọn ọdun sun sori aga nile ọrẹ rẹ fun oṣu marun-un gbako, lẹyin to ti wa ile ti ko si ri nilu Abeokuta.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Ronke Oṣodi: òótọ́ ọ̀rọ̀ máa ń korò gan ni f'áwa èèyàn

Ogungbile fi ilu Eko silẹ lọ si Abeokuta, lẹyin to riṣẹ kan pẹlu ijọba ipinlẹ Ogun. ṣugbọn ko ri ile gba bo tilẹ jẹ pe, o ni owo rẹ dani, gbogbo da lori wipe ko si nile ọkọ.

O sọ fun ile iṣẹ BBC pe, awọn onile maa n kọkọ beere lọwọ lọwọ oun boya oun ti ṣe igbeyawo.

Oríṣun àwòrán, Gloria Yusuff

O fi kun ọrọ rẹ pe, wọn tun maa n beere pe kin lo de ti oun ko ti fii lọ sile ọkọ nigba ti oun ba da wọn lohun pe, oun ko ti ṣe igbeyawo.

Eleyi maa n jẹ iyalẹnu fun Ogungbile wipe, kinni aise igbeyawo oun ni i ṣe pẹlu ile ti oun n wa.

O ni ọpọlọpọ awọn aṣoju onile lo ṣo fun oun pe, ki oun mu ọrẹkunrin oun wa lati duro gẹgẹ bi ọkọ fun oun, ki oun lee ri ile gba.