Ileya: Saraki, awọn gómìnà rọ aráàlú láti máse sọ ìrètí nù

Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ààrẹ Muhammadu sàlàyé pé ẹ̀sìn níkàn lọ̀nà àbáyọ láti jẹ kí ènìyàn hùwà tó tọ́ sí Ọlọ́run àti ọmọ ẹ̀dá.

Ààrẹ Muhammadu Buhari ti rọ àwọn ọmọ Nàìjíríà láti dìde nínú ìṣòkan ati ìfọwọ́sowọ́pọ̀, kí wọn si yàgò fún ìwà ẹlẹ́yàmẹ̀ya àti ìmọ tara ẹni níkan, kí orílẹ̀-èdè yìí báa lè 'd èbúté ògo.

Ààrẹ Buhari sọ̀rọ̀ ọ̀hún nínú àtẹ̀jáde kan tó ti ọwọ́ olùrànlọ́wọ́ àgbà lórí ìgbóhùn sáfẹ́fẹ́ àti ìpolongo rẹ, Garba Sheu jadé, pẹlu arọwa sàwọn Musulumi lati lo àsìkò àjọyọ̀ ọdun ileya yìí láti wà ni ìrẹ̀lẹ̀ ọkan àti lati yẹ ara wọn wò.

O fi kun pé, ó pọn dandan lati gbìyànjú lati jẹ́ asoju rere fún ẹ̀sìn musulumi àti orílẹ̀-èdè yìí, nípa híwu ìwà tó kógojá ni àyíká wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Ileya: Àgbò wọ́n torí ọjà ẹran mẹ́ta ni wọ́n tìpa lókè ọya torí Boko Haram

Ó tun rán àwọn Musulumi léti pé, àsìkò ọdún Eid-ul-Adha wà láti ránti pé, o ṣe pàtàkì láti fara wọn sílẹ̀ fún ìtọ́ni ẹlẹ́dàá wọn, èyí to fí kọ àyé nípa fifi ara wọn jìn fún ìgbáyé-gbádun ọmọlakeji wọn.

Ààrẹ Muhammadu Buhari sàlàyé pé, ẹ̀sìn níkàn lọ̀nà àbáyọ láti jẹ kí ènìyàn hùwà tó tọ́ sí Ọlọ́run àti ọmọ ẹ̀dá.

Buhari sàlàyé pé ìmọ̀ tara ẹni nìkan, wọ̀bìa àti ìwà àjẹ́bánu ti gba ọkan àwọn ọmọ ènìyàn, to fi jẹ́ pé wọn ti kọ ẹsìn wọn sílẹ̀ láti máà lépa ìfẹ́ ọkan wọn.

Oríṣun àwòrán, Saraki/twitter

Bákan náà ni ààrẹ ilé ìgbìmọ asofin Bukola Saraki, ti rọ awọn ọmọ orilẹ̀-èdè Nàìjíríà láti nífẹ̀ ọmọnikejì wọn lọ́kan, kí wọn gbé ìgbé ayé ìrẹ́pọ̀ àti ìwà àláfíà pẹ́lú gbogbo alábágbé wọn, láì fi tàsìkò ọdun yìí nìkan ṣe.

Saraki sọ èyí di mímọ nínú àtéjáde kan ti àgbẹnusọ rẹ̀, Yusuph Olaniyonu gbe jade, o wa rọ àwọn ọmọ Nàìjíríà kí wọn máse káàrẹ̀ láti máà ṣiṣẹ́ ìtọrẹ àànú, pẹ̀lú adúrà ẹ̀bẹ̀ fún orilẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Ẹwẹ, Gómínà ìpínlẹ̀ Kwara, AbdulFatah Ahmed náà kò gbẹ́yìn nínú àwọn gómìnà to tí ń kí àwọn ọmọ Nàìjíríà kú ọdun, nínú àtẹjáde kan ti àkọwé rẹ feto iroyin, Abdulwahab Oba kọ, ó rọ àwọn Musulumi lati kẹ́kọ̀ọ́ ìfàràji sí gbogbo ìkọ́ni Ọlọrun, ki wọn sì jẹ olùgbóran sí gbogbo àṣẹ̀ Allah àti pé, ó pọndandan láti jẹ àlàbò fun arákùnrín wọn.

Àkọlé àwòrán,

Gomina Abiola Ajimobi ti ìpínlẹ̀ Oyo, Ayodele Fayose Ekiti, Akinwumi Ambode ti ìpínlẹ̀ Eko, Ìbikunle Amosun

Tun wẹ, Gomina Abiola Ajimobi ti ìpínlẹ̀ Oyo, Ayodele Fayose ti Ekiti, Akinwumi Ambode ti ìpínlẹ̀ Eko, Ìbikunle Amosun ti ìpínlẹ̀ Ogun, Raufu Aregbesola ti Ọsun àti Rotimi Akeredolu ti Ondo, ló bá gbogbo Musulumi jákèjádo orilẹ̀-èdè yìí àti káàkiri àgbáyé dáwọ ìdunnu, lóri ọdun iléya to wole dé.

Wọn tun rọ àwọn ọmọ Nàìjíríà láti máse káárẹ̀ nípa orilẹ̀-èdè yìí nitori ìgba ọtun ti dé , wọn wa rọ gbogbo ènìyàn láti túbọ máà gbádúra fún ìtẹsíwájú àti àláfíà Nàìjíríà.

Buhari padà sí Nàìjírìa láti ìlú London

Ninu iroyin ẹwẹ, Aarẹ Muhammadu Buhari pada s'orilẹede Naijiria lẹyin isinmi ọjọ mẹwa nilu London.

Ọkọ baalu ile iṣẹ Aarẹ to gbe Buhari de balẹ si papakọ-ofurufu Nnamdi Azikiwe lalẹ ọjọ Satide l'Abuja.

Wamu wamu lawọn ẹṣọ ologun duro bi awọn alabasiṣẹ pọ Aarẹ ti n kii kaabọ ni papapapakọ-ofurufu l'Abuja.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bi ẹ ba gbagbe, ọjọ kẹta Oṣu kẹjọ yii ni Aarẹ Buhari rinrinajọ lọ si ilu London fun isinmi ranpẹ.

Igbakeji Aarẹ Yemi Osinbajo lo dele fun Aarẹ Buhari nigba ti o wa nilu London.