#ENDSARS: Íjìyà tó tọ́ sí Charles Omotosho ni wọ́n dá fún un - Shogunle

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBí Ọlọ́pàá SARS bá dá ènìyàn dúró kó gbọ́ sùgbọ́n...

Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Eko ti dá òṣìṣẹ́ SARS kan, Inspecor Charles Oluṣọla Ọmọtọshọ dúró lẹ́nu iṣẹ́ látàrí pé ó ńgba ẹgbẹ̀rún márùn-ún Náírà lójú pópó ní agbègbè Ikorodu.

Wọ́n dá òṣìṣẹ́ FSARS yìí dúró lẹ́yìn tí afẹ́fẹ́ fẹ́, tí àṣírí owó tó máa ń gbà tú síta pẹ̀lú bí arábìnrin kan Princess Ifẹ ṣe kéde lórí Twitter rẹ̀ ní ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù kaàrùn-ún wí pé Ọmọtọshọ dẹ́rù yínyìnbọn pa àwọn bí wọn kò bá fún un ní ẹgbẹ̀rún márùn-ún Náírà.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ sí:

'Àwọn SARS ló yìnbọn pa ìyá mi'

Kíni iyatọ tó wà láàrin FSARS àti SARS?

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSARS: Awọn ará ìlú fi ẹ̀rí síta nípa ìrírí wọn

Nínú ìkéde Princess Ife lórí Twitter, ó ní "dájú dájú pẹ̀lú ìrírí mi ó tọ́ láti pe àwọn ọlọ́pàá SARS ní ọ̀daràn.

O ni ''ṣe ni mò ń lọ láti ya sinimá kan ní Ikorodu tí àwọn òṣìṣẹ́ SARS sì dá wa dúró, wọ́n sì ní ká san owó láì nídìí. Wọ́n ní àwọn yóò fi ẹ̀mí wa ṣòfò, ni mo bá fi owó ránṣẹ́ sí àpò owó tirẹ̀ lórí ẹ̀rọ ayélujára kí wọ́n baà lè tọpinpin wọn".

Lẹ́yìn oṣù mẹ́ta tí ẹ̀ka tó ń gbẹ́jọ́ aráàlú ní kánmọ́-kánmọ́ nilé iṣẹ́ ọlọ́pàá (PCRRU) sèlérí láti wádìí ìṣẹ̀lẹ̀ náà tí wọ́n sì jẹ́ kó di mímọ̀ fún àwọn aráàlù, òṣìṣẹ́ SARS náà ti gba ìwé ìdádúró lẹ́nu iṣẹ́ báyìí.

Ẹ̀ka PCRRU fi àtẹ̀jáde tó sàfihàn ìdádúró Charles Omotosho sójú òpó Twitter wọn.

Ẹ̀wẹ̀, kìí ṣe Omotosho nìkan ló jìyà ẹ̀ṣẹ̀, igbákejì ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá tún já ipò àwọn òṣìṣẹ́ SARS mẹ́ta míì tí wọ́n jọ ṣe aṣemáṣe náà walẹ̀ láti ipò Seargent sí Corporal tí wọ́n sì ti gba gbogbo ẹ̀wù àti káàdì ìdánimọ̀ lọ́wọ́ Inspector ti wọ́n dá dúró.

Ọwọ́ ba òsìsẹ́ SARS tó pà akẹ́ẹ̀kọ́ ní Iwo

Image copyright Joshua Adetunji
Àkọlé àwòrán Ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá ti ba ọlọ́pàá SARS tó yìnbọn pa akẹ́ẹ̀kọ́ kan ní ìlú Iwo

Afurasi ọlọpaa kogbereegbe SARS kan to yinbọ pa akẹẹkọ Tunde Nafiu nilu Iwo, nipinlẹ Osun lọwọ sinkun ofin ti ba bayi.

Agbẹnusọ fun ile iṣẹ ọlọpaa Folasade Odoro lo fidi ọrọ mulẹ ninu atẹjade kan.

Ọga agba ile iṣẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria Ibrahim Idris lo paṣẹ pe ki wọn wa ọdaran naa ni kiakia.

Àwọn ọ̀dọ́ dáná sun àgọ́ ọlọ́pàá lorí ẹ̀sùn pé ọlọ́pàá SARS pa ọ̀dọ́kùnrin kan

Ẹwẹ, awọn ọdọ dana sun ilẹ iṣẹ ọlọpaa nilu Iwo nibi ifẹhonu wọn lẹyin ti ọlọpaa SARS yinbọn pa Nafiu.

Agbẹnusọ fun awọn ọlọpaa tun fi kun ọrọ rẹ pe mọkanlelọgbọn ninu awọn to dana sun ile iṣẹ awọn ọlọpaa ni ọwọ ofin ti ba bayii.

Kọmisọnna ọlọpaa nipinlẹ Osun Fimihan Adeoye ṣe abẹwo si Ọba ilu naa, Abdulrasheed Akanbi, ati awọn ẹbi to padanu ọmọ to padanu ẹmi rẹ ni Ileogbo ba wọn kẹdun, o si bu ẹnu atẹ lu bi awọn ọdọ ṣe lọ da ina sun agọ ọlọpaa naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀjọ Ọlọ́pàa Naijiria: A ó fi òsìsẹ́ SARS tó se isẹ́ ibi náà jófin

Amọ nibayii, alafia ti pada si agbeegbe naa.Àwọn ọ̀dọ́ ìlú Iwó ti dáná sun àgọ́ ọ́lọ́pàá tó wà ní ìlú náà lówùrọ̀ ọjọ́ ẹtì.

Èyí wáyé lẹ́yìn tí wọ́n fẹ̀sùn pípa ọ̀dọ́kùnrin kan ní ìlú Iwo kan àwọn ọlọ́pàá kògbéregbè SARS ní ọjọ́rú ọ̀sẹ̀.

Olóògbé náà tó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ni ìròyìn sọ wí pé ó ń bọ̀ láti Olupọnna, ìlú kan tí kò jìnà sí Iwo níbi tí ó ti ṣagbákò ikú ọ̀sán gangan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Wọ́n ní àwọn ọlọ́pàá SARS ọ̀hún na pápá bora kúrò níbi tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé lẹ́yìn tí wọ́n yìnbọn pa arákùnrin náà.

Bákan náà ni àwọn ọlọ́pàá tó wà ní àgọ́ náà fórí ara wọn pamọ́ kọ́wọ́ má bàà tẹ̀ wọ́n.

Gẹ́gẹ́ bí oníròyìn kan tí kò fẹ́ dárúkọ ara rẹ̀ ṣe sọ ọ́, "akẹ́kọ̀ọ́ ni ẹni tí wọ́n pa yìí ṣùgbọ́n mi ò le sọ ilé ìwé rẹ̀.

Yínyínbọn síra ẹni wáyé lánàá láàrín ọlọ́pàá kògbéregbè SARS àti àwọn onípàáǹle kan tí ìbọn sì bá akẹ́kọ̀ọ́ náà".