Lẹ́yìn tó forí lakú, Bamidele Ọpẹyẹmi padà sí Nàìjíríà

MOB n ki awọn ololufẹ rẹ

Oríṣun àwòrán, timenewsng

Àkọlé àwòrán,

Micheal Ọpẹyẹmi Bamidele ni oludari eto ipolongo fun gomina ti wọn dibo yan nipinlẹ Ekiti, Kayọde Fayẹmi

Lẹyin to fara ko ọta ibọn ọlọpaa kan lasiko ipolongo ibo fun oludije fun ipo gomina ipinlẹ Ekiti labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu APC .

Micheal Ọpẹyẹmi Bamidele to jẹ oludari eto ipolongo fun gomina ti wọn dibo yan nipinlẹ Ekiti, Kayọde Fayẹmi ti pada si orilẹede Naijiria lati oke okun ti wọn gbee lọ fun itọju.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nibi ti ọlọpaa n gbiyanju ati daabo bo awọn oloṣelu lasiko ti wọn lọ ki awọn aṣaaju ẹgbẹ oṣelu kan ni olu ileeṣẹ ẹgbẹ oṣelu APC nilu Ado Ekiti ni ibọn ba bamidele Ọpẹyẹmi lọwọ ti o si ba eeyan miran ni aya.

Oríṣun àwòrán, timenewsng

Àkọlé àwòrán,

Bi o tilẹ jẹ wi pe Bamidele Ọpẹyẹmi loore ọfẹ ati wa laye loni, ọrọ ko ri bẹẹ fun ẹni keji ti ọpọ eeyan ko mọ orukọ rẹ titi di oni yii.

Bi o tilẹ jẹ wi pe Bamidele Ọpẹyẹmi loore ọfẹ ati wa laye loni, ọrọ ko ri bẹẹ fun ẹni keji ti ọpọ eeyan ko mọ orukọ rẹ titi di oni yii.

Nnkan bii agogo mẹta abọ ọsan ọjọbọ ni Bamidele Ọpẹyẹmi gunlẹ si papakọ ofurufu Murtala Mohammed nilu Eko.