South Africa:Ọpọ àlejò ló fara káása nínú wàhálà túntun
Ọ́lọ́pàá ti mú ènìyàn mẹ́tàdínlọgbọn tó lọ́wọ́ nínú ìwà jàgídíjàgan àti olè jíja tó wáyé.
-
Reuters
Ọ̀kan lára àwọn Somali to ní sọọbu tó ṣeṣe. Orilẹ̀-èdè South African jk ibùgbé fún sps àwọn àtìpò ni àgbáyé
-
AFP
Àwọn tó ń fẹ̀hónú han fọn sí ìgboro lẹ́yìn tí wọn fẹ̀sùn kan pé àwọn to ní iss ń ta àyéderun ọja àti àwọn nkan ti ọjọ ori ti pẹ́ kajá àlà., ìròyìn sọ pé ǹkan tun buru síi nígbà ti ọmọ Somali kan yìnbọn pa ọdọmọde kan to ń gbìyànjú àti jí ọja rẹ̀.
-
AFP
Ọkan nínú àwọn sọọbu àwọn atìpó tí wọn já, tó fi mọ èyí tó jk ti ọmọ Ethopia. Ọps àwọn to ní sọọbu ló fẹ́sẹ̀ fẹe lẹ́yìn ti wọn kó erù ti wọn lé kó dání.
-
AFP
Ọlọ́pàá ti mú ènìyàn mẹ́tàdínlọgbọn tó lọ́wọ́ nínú ìwà jàgídíjàgan àti olè jíja tó wáyé. Èyí rán ọ̀pọ̀ ọmọ South Africa léti ìpanìyan nípakúpa tó wáyé nínú oṣù karun-ún ọdun 2008, ìròyin BBC fi han nígbà náà pé ènìyàn méjìlélọgọta ló pàdánù ẹmi wọn, mọkanlélógójì jẹ́ àjòjì nígbati àwọn mọkànlélógún jẹ ará South Africa.
-
AP
Àwọn oṣìṣẹ́ agbófinró ń ṣewadìí ẹni to yìnbọ lágbègbè náà, wọn ni àwọn nílò láti mú sps àwọn ti igbá srs náà bá ṣi mọ lóri.
-
AFP
Wọn ti rọ àwọn to ní sọọbu lati tí ibusọ wọn fun ìgba diẹ lkyìn ti \iṣẹlẹ̀ náà ṣẹlẹ, bákan náà ní ètò ààbò tún gbópọn sí lágbègbè náà.
-
AFP
Ọpọ̀ àwọn tó ní sọọbu lẹ̀rù ń ba láti pada sí ibùṣọ wọn nítori rògbòdìyan míràn tún lèè bk silẹ̀. '' kò si ìjọba níbí , ti ìjọba bá wà ni gbogbo ǹkan yìí ní wọn o móju to'' ẹnikan ló sọ ọ̀rọ̀ yìí.
-
AFP
Ìberu bojo wà gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sẹlẹ̀ lọ̀dún 2008, rògbòdìyàn náà le tàn dé àwọn apá ibòmíràn lórilẹ̀-èdè South Africa, gẹ́gk bí akọròyìn wa ṣe sọ
-
AFP
Awọn alaṣẹ ìjọba ni àwọn ń bóju wo ẹsùn ti wọn fi kàn pé wọn ń ta ayederu ọja fún ara ìlú