Buhari: A lágbára láti san gbogbo gbèsè tí a jẹ

Aworan Aarẹ Buhari nibi ipade Afirika ati China ni Beijing

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ààrẹ Muhammadu Buhari wa lorílẹ̀èdè China làti lọ se ìpàdé tó dá lórí ìbásepọ̀ láàárín ilẹ̀ Afirika ati China.

Ààrẹ orílẹ̀èdè Nàìjíríà, Muhammadu Buhari ti fèsì sọrọ to n ja ràìnràìn nipa ẹ̀yáwó $328 million ti Nàìjíríà fẹ yà lọ́wọ́ orílẹ̀-èdè China.

Loju opo Twitter rẹ o sọ wi pe ki awọn eeyan ma se ka ọrọ ti awọn kan n sọ wipe panpẹ ni ẹ̀yáwó $328 million ti Nàìjíríà fẹ yà lọ́wọ́ orílẹ̀èdè China jẹ kun.

''Orileede Naijiria lagbara ti o si setan lati san gbogbo owo ti wọn ba ya pada nigba to ba yẹ ni ibamu pẹlu eto inawo to yanranti.''

Buhari so pe ibasepọ laarin Naijiria ti orileede China laarin ọdun mẹta sẹyin ti se okunfa sise isẹ lori awọn nnkan amayerọrun orisirisi ti owo wọn le ni billionu maarun dola.

O ni laipe yi ni Naijiria ati China buwọlu iwe adehun lati fikun ise lori ọkọ oju irin ti wọn sẹsẹ se ati lori ètò ìbáraẹnisọ̀rọ̀ àti ìmọ̀ ẹ̀rọ.

Laipe yi ni iroyin kan ti awọn kan si bẹnu atẹ lu bi Aarẹ Buhari ti se fẹ gba ẹ̀yáwó $328 million lọ́wọ́ orílẹ̀èdè China.

Ẹ̀yáwó yí jẹ́ àfikún un gbèsè $73 billion tí orílẹ̀èdè Nàìjíríà ti ń jẹ tẹ́lẹ̀.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nínú àtẹ̀jáde tí ilé iṣẹ́ ààrẹ gbé jáde lọ́sẹ̀ tó kọjá, wọ́n ṣàlàyé wí pé ó wà láàrin ilé iṣẹ́ Galaxy Backbone ti Nàìjíríà àti Huawei Technologies ti China fún ìdàgbàsókè ìbaraẹnisọ̀rọ̀ àti ìmọ̀ ẹ̀rọ gẹ́gẹ́ bí àlàkàlẹ̀ ètò ìṣèjọba ààrẹ Buhari.

Buhari ṣe ìpàdé pẹ̀lù àwọn ọmọ Nàìjíríà ní China

Aarẹ orileede Naijiria Muhammadu Buhari ti se ipade pẹlu awọn ọmọ Naijiria to wa ni orileede China.

Nibi ipade naa,o fi da wọn loju pe oun ko ni ifoya nipa sise eto idibo eleyi toyanrantin

''Eru idibo ti ko lẹjanbakan ninu ko ba mi nitori iru idibo bẹẹ lo gbemi wọle''

Loju opo Twitter iile isẹ ijọba orileede Naijiria ni fọnran fidio ti Aarẹ Buhari ti sọ ọri yi wa.

Oríṣun àwòrán, @NGRPresident

Àkọlé àwòrán,

Ìpàdé FOCCAC yoo ma jiroro lori ọna ati tunbọ mu idagbasoke ba orileede Afrika ni ifọwọsowopọ pẹlu China

Ipade oun to waye ni ile ise orileede Naijiria ni China ni akọkọ ipade Buhari lati igba to ti gunlẹ si China fun ipade ẹlẹẹkeje ti yoo waye ni ọjọ kẹta si ikẹrin ni Beijing.

Awọn aworan miran re lati ibi ipade naa:

Oríṣun àwòrán, @NGRPresident

Àkọlé àwòrán,

Aworan yi se afihan Aarẹ Buhari pẹlu awọn ọmọ Naijria ni China to n kẹkọ nipa irinajo ọkọ oju irin

Oríṣun àwòrán, @NGRPresident

Àkọlé àwòrán,

Asisat Oshola agbabọọlu OBINRIN Naijiria to n gba bọọlu jẹun ni China naa sọrọ nibi ipade oun

Sẹnetọ mẹrin ati Gomina Ipinle Akwa Ibom tẹlẹri, Godswill Akpabio to sẹsẹ kuro ni ẹgbẹ oselu APC lọ si PDP wa lara awọn to tẹle Aarẹ Muhammadu Buhari lọ si China.

Awọn minisita mẹsan ati gomina mẹrin lati ẹgbẹ oselu PDP naa wa lara awọn adari osisẹ ijọba to tẹlẹ Aarẹ Buhari.

Orukọ awọn ti yoo tẹle Aarẹ Buhari lọ si China.

 • Gomina ipinlẹ Eko, Akinwunmi Ambode
 • Gomina ipinlẹ Bauchi, Mohammed Abdullahi Abubakar
 • Gomina ipinle Jigawa, Mohammed Badaru Abubakar
 • Gomina ipinle Imo, Rochas Anayo Okorocha
 • Sẹnetọ to n soju ipinlẹ Nasarawa, Abdullahi Adamu
 • Sẹnetọ to n soju ipinlẹ Benue, George Akume
 • Sẹnetọ to n soju ipinlẹ Sokoto, Aliyu Wamakko
 • Minisita fun ọrọ okeere, Geoffrey Onyeama,
 • Minisita fun eto irina ọkọ, Rotimi Amaechi,
 • Minisita fun ọrọ ile ati ẹrọ mọnamọna, Babatunde Fashola,
 • Minisita olu ilu Naijiria, Muhammed Bello,
 • Minisita fun ọrọ aje, Okechukwu Enelemah,
 • Minisita fun ọrọ eto isuna, Udoma Udo Udoma
 • Minisita fun ipese omi ati alumọni, Suleiman Adamu
 • Minisita ipinlẹ fun ọrọ epo rọọbi, Ibe Kachikwu
 • Minisita ipinlẹ fun ọrọ irinajo ofurufu, Hadi Sirika
 • Oludamọran fun eto aabo lorilẹede Naijiria, Babagana Monguno
 • Oludari fun eto iwadii lorilẹede Naijiria, Ahmed Abubakar
 • Adari fun Ajọ NNPC, Maikanti Baru.
Àkọlé fídíò,

'Wiwa ọkọ Baalu da bi ki ẹ lọ da duro sori apata'