2019 Election: Ẹgbẹ́ ọmọ Nàìjíríà fún Buhari ní fọ́ọ̀mù lọ́fẹ̀ẹ́

Buhari

Oríṣun àwòrán, @Basir Ahmad/Twitter

Àkọlé àwòrán,

Ni asiko ti aarẹ Buhari fi wa ni orilẹ-ede China ni awọn eeyan kan ko ara wọn jọ lati ra fọọmu fun Buhari

Aarẹ orilẹ-ede Naijiria, Muhammadu Buhari ti tẹ'wọ gba fọọmu ti awọn ọmọ ẹgbẹ kan gba fun un ní iye mílíọ̀nù mẹ́rìnléláàdọ́ta naira lati dupo aarẹ ni 2019.

Ni ile aarẹ to wa nilu Abuja ni awọn ọmọ ẹgbẹ naa ti gbe fọọmu ti wọn gba lorukọ aarẹ Buhari naa fun un.

Ni asiko ti aarẹ Buhari fi wa ni orilẹ-ede China fun ijiroro lori ọrọ okoowo ati ọrọ aje ni awọn eeyan kan ko ara wọn jọ labẹ ẹgbẹ kan ti wọn pe orukọ rẹ ni National Consolidation Ambassadors Network (NCAN) lati ra fọọmu ati du ipo aarẹ labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu APC fun un.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bi ẹ ko ba ni gbagbe, aarẹ Buhari funrarẹ ti kọ́kọ́ ke gbajare sita pe oun ko lee san miliọnu marundinlaadọta naira ti ẹgbẹ oṣelu APC gbe le fọọmu ipo arẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu naa, eleyi lo si sun ẹgbẹ naa lati gbe igbesẹ yii, gẹgẹ bi wọn ṣe sọ.

Ohun ti a gbọ ni pe, oniruuru ẹlẹgbẹjẹgbẹ ni wọn ti n ṣubu lu ara wọn lati ra fọọmu yii fun aarẹ ki ọrọ ọhun to ja mọ ẹgbẹ National Consolidation Ambassadors Network (NCAN).

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Buhari ti gba fọ́ọ̀mù láti dupò ààrẹ ọdún 2019

Idi ti ẹgbẹ NCAN fi ra fọọmu fun Aarẹ Muhammadu Buhari

Ní ọjọ́ ìṣẹ́gun ọjọ́ kẹta oṣù kẹ́sàán ọdún 2018 ní ẹgbẹ òṣèlú All Progressive Congress (APC) gbé owó tí àwọn tó bá nífẹ láti dupò níbi ìdìbò gbogboogbo ọdún 2019 yóò san jade.

Lẹ́yìn eyí ní ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ti ń sọ pé ìgbéṣẹ̀ ẹgbẹ òṣèlú APC kò fí ti mẹ̀kúnù àti t'àwọn ọ̀dọ́ ṣe.

Àkọlé fídíò,

Owó fọ́ọ̀mù APC fún ipò Ààrẹ gọbọi- olùdíje

Lósàn ọjọ́ tó tẹ̀lé e ní àwọn ẹgbẹ́ kan tí wọn pé ara wọn ní ọmọ Nàìjíríà dáradára rá fọ́ọ̀mù fún ààrẹ láti díje lọ́dún 2019 gẹ́gẹ́ bi ààrẹ Nàìjíríà.

Oríṣun àwòrán, Ahmed Bashir/twitter

Àkọlé àwòrán,

Buhar tí gbà fọ́ọ̀mù fún ìdupò ààrẹ ọdún 2019

Gẹ́gẹ́ bí àgbénúsọ fún ààrẹ lóri ìbánisọ̀rọ̀ ìgbàlódé Bashir Ahmad ṣe sọ lóri àtẹ̀jíṣẹ́ twitter rẹ pé àwọn ẹgbẹ́ rere ọmọ Nàìjíríà kan ló ra fọ́ọ̀mù náà fún ààrẹ Buhari

Ààrẹ ẹgbẹ́ òṣèlú APC Adams Oshiomole ló gba àwọn ẹgbé ọ̀hún sí ilé ẹgbẹ́ lásìkò tí wọn wá ra fọ́ọ̀mù náà lórúkọ ààrẹ.

Àwọn ọmọ Nàíjíríà tí bẹ̀rẹ̀ sí fèsì báyìí lóri ríra fọ́ọ̀mu ọ̀hún.

Ọmọ ẹgbẹ́ APC wọ́ APC lọ ilé ẹjọ nítori owó fọ́ọ̀mù

Ọ̀kan nínú àwọn tó ń gbèrò láti díje sípò ààrẹ orilẹ̀-èdè Nàìjíríà Christmas Akpodiete nínú ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressive Congress tí wọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC si lọ sílé ẹjọ kan l'Abuja ló bí owó fọ́ọ̀mù ìfèróngbà hàn ṣe ṣe gọbọi.

Ó bẹ ilé ẹjọ́ láti jẹ kí ẹgbẹ òṣelú APC dáwọ́ ìpàdé yíyan ẹni tí yóò sojú ẹgbẹ náà tí wọn ń pinu láti ṣe dúró nítorí owó fọ́ọ̀mù náà ti pọ̀jù.

O ní ti wọn bá sì tẹ̀síwájú láti ṣe ìpádé náà kí ilé ẹjọ́ fagile e.

Akpodiete tún rọ ilé ẹjọ́ lati dènè àjọ elétò ìdìbò lati rí àbájáde ìpàdé ẹgbẹ gẹ́gẹ́ bí èyí tó tọ̀nà.

Ó ní owó tí ẹgbẹ́ oṣèlú náà gbé lé fọ́ọ̀mù kò pánilẹ́rìn níkàn bíkòṣe pé kò tún ṣee kọlù, bákan náà kò bá òfin mú pẹ̀lú.

Akpodiete ní kíni ànfàni ofin ẹnikẹni ò kéré jù láti dupò (NOT TOO YOUNG TO RUN) nítori wọn ń pinu lati fi ọwọ́ ọlá gbá àwọn ọdọ́ orílẹ̀-èdè yìí lójú ni.

APC pàdánù ọmọ MKO Abiọla

Oríṣun àwòrán, Facebook/Rinsola Abiola

Ọ̀kan lara awọn ọmọbinrin oloogbe MKO Abiọla, Rinsọla Abiọla ti fi ẹgbẹ oṣelu APC silẹ.

Ninu lẹta kan to kọ ranṣẹ si alaga wọọdu idibo rẹ, eyi to tẹ wa lọwọ loju opo Twitter rẹ, Rinsọla ni igbesẹ ohun lati fi ẹgbẹ silẹ ko ṣẹyin ofin tuntun ti awọn oludari ẹgbẹ All Progressives Congress, APC, fi sita l'ọjọ Aje.

O ni irinajo ọdun maarun pẹlu ẹgbẹ osẹlu naa jẹ eyi to kun fun ẹ̀ka ti ko ṣe e gbagbe.

Bi o tilẹ jẹ wipe awọn kan n sọ lori ayelujara Twitter pe ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, ni Rinsọla darapọ mọ, arabinrin naa ni oun ko ti darapọ mọ ẹgbẹ́ oṣelu kankan.

Ati pe awọn nkan bi fifi aaye gba awọn obinrin ati ọ̀dọ́, to fi mọ iṣejọba awa-arawa l'abẹle, ni yoo sọ ẹgbẹ oṣelu ti oun yoo pada darapọ mọ.

O ni ki awọn alaṣẹ ẹgbẹ oṣelu PDP ṣi fi ara balẹ naa.