PDP ta ohùn padà sí ààrẹ̀ Buhari lórí àwọn arìnrìnàjò Nàìjíríà ní Germany

PDP ta ohùn padà sí ààrẹ̀ Buhari

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

PDP ta ohùn padà sí ààrẹ̀ Buhari

Ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party ti bu ẹnu àtẹ́ lu bí ààrẹ́ Buhari ṣe ní àwọn ọmọ Nàìjíríà tó bá lọ ilẹ̀ Europe lọ́nà àìtọ̀ yóò dáhùn fún ara wọn.

Lẹ́yìn tí ààrẹ Buhari sọ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí ààrẹ orílẹ̀èdè Germany pé ọmọ Nàìjíríà tí ọwọ́ bá tẹ̀ nínú ìgbìyànjú rẹ̀ láti wọ ilẹ̀ Europe lọ́nà àìtọ́ ni yóò dáhùn fún ara rẹ̀.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ sí:

Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP fèsì sí èyí lójú òpó Twitter wọn wí pé " èyí kan ńfi ààrẹ Buhari han gẹ́gẹ́ bí adarí tí kó ní ìmọ̀lára fún ẹni tí kò sì bìkítà nípa ohun tí àwọn to ní ìfọkàn tán sí i.

Sí èyí, ọpọ̀lọpọ̀ ọmọ Nàìjíríà ti ń fèsì yálà ní àtìlẹ́yìn ẹgbẹ́ òṣèlú PDP tàbí lòdì sí ohun tí wọ́n sọ.