Ilé wó lé àwọn olùjọ́sìn ìjọ Kátólìkì lórí ní Delta

ìjọ tó wó lulẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ẹ̀mí ọmọdé kan nù nínú ìjọ tó wó lulẹ̀

Ilé ìjọsìn Kátólìkì kan ti wó mọ́ àwọn olùjọ́sìn lórí lónìì ọjọ́ Àìkú ọjọ́ kejì OṢÙ Kẹ́sàn án ọdún 2018.

Nígbà tí BBC bá Kọ́mísánà Ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà, Muhammed Mustapha sọ̀rọ̀ ló fi àrídájú hàn pé ọmọdékùnrin kan pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Bákan náà, Kọ́mísánà jẹ́ kó di mímọ̀ pé ilé ìjọsìn náà ti lé lọ́gọ́rùn ún ọ̀dún ó sì ti rí bíi ilé àlàpà.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ sí:

Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ olùjọ́sìn ìjọ Kátólìkì Pọ́ọ̀lù míma ti ìlú Ugolo, Adagbrasa ní ìjọba ìbílẹ̀ Okpe ní ìpínlẹ̀ Delta ló wà nínú ilé ìjọsìn náà nígbà tó wó lé wn lórí.

Ní àkókò tí a kó ìròyìn yìí jọ, kò tíi sí àrídájú iye ènìyàn tó fara pa sùgbọ́n ohun tí àwọn olùgbé ìlú náà sọ fún àwn oníròyìn ni pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé lákòkò ìsìn.

Àkọlé fídíò,

'Agogo méje ń lọ lù láàrọ̀ la gbọ́ ariwo ńlá kan'