Àwọn aṣájú ẹgbẹ́ awakọ̀ RTEAN ń sọ̀kò ẹ̀bi lóríi ìkọlù tó ń wáyé láà'rín ẹgbẹ́ naa

Àkọlé fídíò,

Àwọn aṣájú ẹgbẹ́ awakọ̀ RTEAN ń sọ̀kò ẹ̀bi lóríi ìkọlù tó ń wáyé láà'rínẹgbẹ́ naa

Èèyàn 11 f'ara gbọgbẹ́ nínú ìkọlù RTEAN l'Ekiti

Rogbodiyan to n waye laarin awọn ọmọ ẹgbẹ awakọ ero RTEAN nipinlẹ Ekiti ko tii ṣebi eyi ti o ti j rodo lọ mumi o.

Awọn aṣiwaju ẹgbẹ awakọ ero RTEAN nipinlẹ Ekiti ti wọn wa nidi wahala ati ikọlu to n waye lẹnu lọwọlọwọ yii laarin awọm ọmọ ẹgbẹ naa ni ipinlẹ ọhun ṣi n di ẹbi 'iwọ lo jẹbi, emi kọ" ti wọn si n leri leka pe awọn ko lee simi agbaja ayafi ti ẹnikeji naa ba dawọ tirẹ duro.

Amọṣa ninu ohun gbogbo ti awọn mejeeji yii, Rotimi Ọlanbiwọnninu ati Isaac Fatimẹhin n sọ, o fihan gbangba pe ipo ni o fa wahala sileẹ ninu eyi ti eeyan mọkanla ti di ero ileewosan bayii.

Jakejado Naijiria, paapaa lẹkun iwọ oorun gusu orilẹede Naijiria ni ọrọ gbigba akoso ẹgbẹ awakọ ti maa n ho oruyeye tpẹlu ọpọlọpọ itajẹsilẹ eleyi ti ẹmi si tun maa n lọ si ni igba miran.

Àkọlé àwòrán,

Gẹgẹ bii ohun ti BBC Yoruba gbọ, pupọ awọn eeyan wọnyii ni wọn ṣa lọgbẹ ada lasiko wahala naa

Ko din ni awọn ọmọ ẹgbẹ ọlọkọ ero RTEAN mọkanla ti wọn fara ṣeṣe yannayanna ni irọlẹ ọjọ aiku lasiko wahala kan to waye lori yiyan olori ẹgbẹ naa.

Gẹgẹ bii ohun ti BBC Yoruba gbọ, pupọ awọn eeyan wọnyii ni wọn ṣa lọgbẹ ada lasiko wahala naa.

Ọgbẹni Fatimẹhin Isaac to jẹ alaga ẹgbẹ awakọ ero RTEAN lẹkun iwọ oorun gusu orilẹede Naijiria salaye wi pe lati ọjọ abamẹta ni awọn ọmọ ẹgbẹ naa kan ti n kọlu awọn ọmọ ẹgbẹ to jẹ ọmọlẹyin rẹ.

Ọgbẹni Fatimẹhin n fi ẹsun kan ọgbẹni Ọlanbiwọnnu ti ọpọ mọ si Mentilo gẹgẹ bii ẹni to n lewaju awọn janduku ti wọn ko ibọn ati ada dani lati wa kọlu awọn eeyan rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:Èèyàn 11 f'ara gbọgbẹ́ nínú ìkọlù RTEAN l'Ekiti

Bi ọrọ ṣe bẹrẹ

Bi ẹ ko ba ni gbagbe, ni ọjọ aje to tẹle idibo nipinlẹ Ekiti lawọn ọmọ ẹgbẹ ọlọkọ ero kan ti ya si igboro lati yi ijọba ẹgbẹ naa pada.

Gẹgẹ bi wọn si ti ṣe sọ fun ikọ BBC Yoruba nigba naa, bi o ti ṣe di wi pe wọn ti dibo yan eeyan tuntun lati di ipo gomina mu nipinlẹ naa, o di dandan ki ayipada naa o de ba ẹgbẹ ọlọkọ ero nibẹ.

Bi o tilẹ jẹ wi pe ero araalu lẹyin ọjọ naa ni pe nnkan ti pada sipo alaafia laarin ẹgbẹ naa, ohun ti a gbọ ni pe ọrọ tani yoo di alaga ẹgbẹ naa lo fa wahala ati ikọlu akọtun yii.

Àkọlé fídíò,

Ekiti Election: Ẹgbẹ́ awakọ̀ Ekiti pa ìjọba dà lẹ́yìn tí wọ́n kéde Fayẹmi

Amọṣa Ọgbẹni Ọlanbiwọninu ti inagijẹ rẹ n jẹ Mentilo ti ni ko si ootọ ninu ọrọ naa ati pe oun gan an lo n sa ere bi ina aawọ to wa laarin ẹgbẹ naa yoo ṣe ku.

Awọn eeyan mọkanla ti o fara kaaṣa ikọlu aarin ẹgbẹ ọlọkọ ero naa ni a gbọ pe wọn ti wa ni ile iwosan bayii.