Khadijat ni awakọ̀ Bàálù àkọ́kọ́ láti Ọffa

Bi eeyan ba kọkọ ri Khadijat Olabanke Adigun o seese ki o lero wi pe ko ni nnkankan se pẹlu ọkọ baalu wiwa.

Sugbọn nigba ti ẹ ba fi ma da ọrọ baalu silẹ letigbọ rẹ, se ni ohun rẹ yoo yatọ.

''Lati igba ti mo wa ni kekere ni mo ti nifẹ si baalu wiwa. Gbogbo ara ati ọrẹ lo si mọ wi pe ti Banke ba ti ri baalu, se ni mo ma ma kọrin baalu odaabọ, ba mi ki iya mi ẹlẹkọ''

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ sí:

Ifẹ ti Khadijat ni fun ọkọ baalu yii ti di ooto pẹlu bi o ti se gba iwe ẹri di awakọ̀ òfurufú obìnrin àkọ́kọ́ tó wá láti ẹkùn gúusù ìpínlẹ̀ Kwara.