Women issues: Lara Kudayisi: Ọ̀kùnrin mẹ́rìnlá fimí dárà tí kò dára rí ṣùgbọ́n mo padà borí ìrònú

Women issues: Lara Kudayisi: Ọ̀kùnrin mẹ́rìnlá fimí dárà tí kò dára rí ṣùgbọ́n mo padà borí ìrònú

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni àwọn ènìyàn máa ń na ìka àléébù sí obìnrin tó bá ti bímọ rí tó sì tún ṣe ìpinu láti fẹ́ ọkọ́ tàbí ṣègbéyàwó alárédé.

'Ìjákulẹ̀ ọkùnrin ló sọ mí di alárinà'

Mo máa ń ti ara mi mọ́ ọkùnrin lọ́rùn- Lara Kudayisi

Lara Kudayisi to jẹ gbajugbaja alarina fun ọkunrin ati obinrin ṣalaye ohun ti oju rẹ ti ri laye ko to pada wa jẹ eeyan lawujọ.

Lara tun gba awọn obinrin to ti bi ọmọ ri laiṣẹ igbeyawo nimọran pe ki wọn má ro ara wọn pin.

O sọ iriri rẹ bi oun ṣe bimọ ni ẹni ọdun mokandinlogun ki o to pada fẹ ọkọ to wu u.

Bakan naa ni Lara rọ awọn Obi lati dẹkun sisọ ọrọ kobakungbe si awọn ọmọ wọn to ba ṣe aṣiṣe ri.

Lara n rọ awọn ọdọbinrin lati gbe igbe aye ti ko ni mu ibanujẹ dani ni ọjọ ola.

O tun gab wọn nimọran lati maṣe ro ara wọn pin nitori pe ọjọ ọla wọn yoo dara ni kete ti o ba ti yi iwa rẹ pada ni ibamu pẹlu iwa iru ọkunrin to wu ọ lati fẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ sí: