Ìdìbò 2019: kò s'ọ̀dọ́ tó lè ra fọ́ọ̀mù ipò Ààrẹ ní #45m

Ìdìbò 2019: kò s'ọ̀dọ́ tó lè ra fọ́ọ̀mù ipò Ààrẹ ní #45m

Olùdíje fún ipò aṣojú-ṣòfin àgbà l'Abuja Kolawole Temitope to fẹ soju ẹka idibo Okitipupa-Irele nipinlẹ Ondo sọ pé #45m owo rira fọọmu fun awọn oludije fun ipo rẹ ninu ẹgbẹ oṣelu APC ti pọju.

Temitope to ba BBC Yoruba sọrọ fidi rẹ mulẹ pe ọgbọn a ti dena awọn ọdọ lati dije ninu idibo aarẹ ọdun 2019 ni ẹgbẹ APC n da lo jẹ ki wọn gbowo gọbọi le fọọmu naa.

Temitope sọ pe o ṣeeṣe ki ẹgbẹ naa ti ni awọn ti wọn fẹ ki wọn dije lọkan ki wọn to kede owo naa.

O ni kosi ọdọ kankan to le ri iru bayii lati ra fọọmu idije fun ipo kan tabi omiran.