Edwin Clark: iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ ọlọ́pàá 3 tó yabo ilé Clark

Edwin Clark àti Ibrahim Idris

Oríṣun àwòrán, Empics

Àkọlé àwòrán,

Àwọn ọlọ́pàá mẹ́ta ṣiṣẹ́ dáràn lórí bí wọ́n ti yabo ilé Edwin Clark

Orin awa o ran yin niṣẹ ni ile iṣẹ ọlọpaa orilẹede Naijiria fi bọ ẹnu lẹyin ti wọn da mẹta lara awọn ọlọpaa to yabo ile ọtọkulu Edwin Clark duro.

Wọn yabo ile naa lọna aitọ lọjọ Iṣẹgun nilu Abuja lẹnu iṣẹ lori ẹsun pe o ko ohun ija oloro pamọ sile.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Agbẹnusọ fun awọn ọlọpaa ọgbẹni Jimoh Moshood salaye pe awọn ọlọpaa ọhun kọja aye wọn.

Àkọlé fídíò,

'Àwa oní Tíátà kìí dúró nílé, àwọn ọmọ wa nílò wa'

Ọgbẹni Moshood fi kun ọrọ rẹ pe ile iṣẹ ọlọpaa da Godwin Musa, Sada Abubakar ati Yabo Paul duro nitori iwa arufin ni wọn wu.

O salaye pe ọga to dari wọn lọ si ile ọgbẹni Mark, ASP David Dominic ti n sọ tẹnu rẹ bayii lori ẹsun pe o fiṣẹ silẹ lakoko ti wọn yabo ile ọhun.

Ọgbẹni Moshood sọ pe afaimọ kiṣẹ maa bọ lọwọ ASP Dominic naa nigba ti iṣẹ iwaadi to n lọ lori rẹ ba pari.

Ṣugbọn awọn eeyan ka sọrọ loju opo Twitter wọn awọn kan lati ile iṣẹ ọlọpaa ni wọn niṣẹ, wọn sọ pe wọn da jisẹ ara wọn.

Ọrọ naa ti ẹ di arajiyan laarin awọn awọn kan lori opo Twitter lẹyin t'ẹnikan sọ pe ki ile iṣẹ ọlọpaa gbe fọtọ awọn ti wọn duro sita, ṣugbọn awọn ẹlomiran ni ayederu fọto ni wọn o gbe jade wipe ki wọn maa ṣe iyọnu.