NLC, TUC: Wàhálà ni Fayoṣe ń fà lẹ́sẹ̀ pẹ̀lú owó àmúrelé N75m tó yà fún ara rẹ̀

NLC, TUC: Wàhálà ni Fayoṣe ń fà lẹ́sẹ̀ pẹ̀lú owó àmúrelé N75m tó yà fún ara rẹ̀

Ẹgbẹ oṣiṣẹ nipinlẹ Ekiti ti bu ẹnu atẹ lu Gomina ipinlẹ naa, Ayọdele Fayoṣe lori ẹsun pe o ra ọkọ ayọkẹlẹ SUV kan ti owo rẹ to milliọnu mẹrinlelaadọrin naira fun ara rẹ, pẹlu pe o tun ya owo to to milisnu mẹrinlelogoji fun ara rẹ gẹgẹ bii owo amurele fun ifẹyinti.

Ibinu awọn oṣiṣẹ ni ipinlẹ naa jẹys ninu atẹjade kan eleyi ti agbarijọps ẹgbẹ oṣiṣẹ nipinlẹ naa, NLC ati TUC fi ọwọ si.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn adari ẹgbẹ oṣiṣẹ nipinlẹ Ekiti ni ọrọ naa ko lorukọ meji ju iwa ailaanu ati ikọbiara si iya awọn oṣiṣẹ ati mẹkunu nipinlẹ naa.

Wọn ni iyalẹnu nla gbaa lo jẹ pe gomina ti ko rowo sanwo oṣu awọn oṣiṣẹ lee maa ṣẹṣọ ninu ọkọ ayọkẹlẹ olowo iyebiye ti yoo si tun maa san owo amurele fun ara rẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Olùdámọ̀ràn fún gómìnà ìpínlẹ̀ Ekiti Lere Olayinka sọ pé ẹ̀bùn ọkọ̀ #75m fún Fayose lẹ́tọ̀ọ́ lábẹ́ òfin

Amọṣa wọn ti fi ikilọ lelẹ pe bi gomina fayoṣe ba tẹ siwaju lati san owo gọbọi naa fun ara rẹ ati igbakeji rẹ, ọrọ naa yoo lẹyin bi oku iya jọjọ ni o, nitori awọn ko ni kuna lati da omi alafia lagbo iṣẹ ọba ru nipinlẹ naa nipa gigunle iyanṣẹlodi.

Iroyin lu si igboro pe gomina Ayọ Fayoṣe ti yoo fi ipo iṣejọba silẹ ni oṣu kẹwa ọdun 2018 ti buwọlu ẹgbẹlẹgbẹ owo fun rira ọkọ ayọkẹlẹ fun ara rẹ ati owo amurele fun oun ati igbakeji rẹ; ṣugbọn agbẹnusọ fun gomina Fayoṣe, Yọmi Layinka ti ṣalaye fun BBC Yoruba pe, ko soun to buru ninu eyi nitori bi alara ti ṣee niyi ko si yẹ ko hun ajero. O ni awọn gomina to ṣaaju Fayoṣe naa ti gba irufẹ ẹbun bẹẹ ti ko si hun wọn.

Ayo Fayose: 'ẹ̀bùn ọkọ̀ #75m fún Fayose kìí ṣe tuntun'

Kosi ohun toju o riri ni olùdámọ̀ràn fún gómìnà ìpínlẹ̀ Ekiti Lere Olayinka fi fesi sọrọ to n tan kalẹ pé ijọba Ekiti ti fọwọ si ẹ̀bùn ọkọ̀ #75m Lexus fún gomina Ayo Fayose gẹgẹ bi ẹbun amurele bi ijọba rẹ ti ku diẹ ko tan

Ọgbẹni Olayinka to ba BBC Yoruba sọrọ fidi rẹ mulẹ pe igbesẹ naa lẹ́tọ̀ọ́ lábẹ́ òfin, ati wipe ipinlẹ Ekiti ti ṣe iru rẹ fun awọn kan tẹlẹ ri.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si: