Ìrìnàjò China: Nnkan márùn ún tó ṣẹlẹ nigba tí Buhari ko sì nílé

Aworan Buhari

Oríṣun àwòrán, @Bashir Ahmad

Àkọlé àwòrán,

Lẹyin ti wọn gba fọọmu fun Aarẹ Buhari ni fọọmu gbigba fun awọn to n du ipo ba di asa

Lati igba iwasẹ ni Baale ile ti maa n dari gbogbo eto ile.

Bi baale ile ko ba si si nile,ni kete to ba tajo de, awọn ara ile a ma jabọ oun to sẹlẹ nigba to wa lajo fun.

Eyi lo mu ki a se atupale awọn nnkan to sẹlẹ nigba ti Aarẹ orileede Naijiria Muhammadu Buhari se irinajo lọ si China.

Iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ ọlọ́pàá mẹta tó yabo ilé Clark

Orin awa o ran yin niṣẹ ni ile iṣẹ ọlọpaa orilẹede Naijiria fi bọ ẹnu lẹyin ti wọn da mẹta lara awọn ọlọpaa to yabo ile ọtọkulu Edwin Clark duro.

Wọn yabo ile naa lọna aitọ lọjọ Iṣẹgun nilu Abuja nigba ti Aarẹ Buhari wa ni orileede China .

Oríṣun àwòrán, Empics

Àkọlé àwòrán,

Àwọn ọlọ́pàá mẹ́ta ṣiṣẹ́ dáràn lórí bí wọ́n ti yabo ilé Edwin Clark

Esun tio wwọn fi kan Clark ni pe o ko ohun ija oloro pamọ sile.

Eryinorẹyin lawọn ọlọpa tọrọ aforijin ti won si tu ikọ amuseya lori iwa odaran ile ise ọlọpa ka.

Àwọn olólùfẹ̀ Ààrẹ Buhari kan ra fọ́ọ̀mù 45m naira fún un lati díje dupò ààrẹ lọ́dun 2019.

Ní ọjọ́ ìṣẹ́gun ọjọ́ kẹta oṣù kẹ́sàán ọdún 2018 ní ẹgbẹ òṣèlú All Progressive Congress (APC) gbé owó tí àwọn tó bá nífẹ láti dupò níbi ìdìbò gbogboogbo ọdún 2019 yóò san jade.

Kete si ni ọ̀kan nínú àwọn tó ń gbèrò láti díje sípò ààrẹ orilẹ̀-èdè Nàìjíríà Christmas Akpodiete nínú ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressive Congress wọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC lọ sílé ẹjọ kan l'Abuja lóri bí owó fọ́ọ̀mù ìfèróngbà hàn ṣe ṣe gọbọi.

Àkọlé fídíò,

Owó fọ́ọ̀mù APC fún ipò Ààrẹ gọbọi- olùdíje

Oun nikan kọ.

Ọ̀pọ̀ ènìyàn sọ pé ìgbéṣẹ̀ ẹgbẹ òṣèlú APC kò fí ti mẹ̀kúnù àti t'àwọn ọ̀dọ́ ṣe.

Kí a tó wí, kí a tó fọ ni àwọn ẹgbẹ ọdọ kan ti ko owo kalẹ ra fọọmu ìfèrongbà hàn láti kópa nínú ìdìbò Ààrẹ fún Buhari.

Oríṣun àwòrán, Ahmed Bashir/twitter

Àkọlé àwòrán,

Buhar tí gbà fọ́ọ̀mù fún ìdupò ààrẹ ọdún 2019

Lẹyin ti wọn gba fọọmu fun Aarẹ Buhari ni fọọmu gbigba fun awọn to n du ipo ba di asa.

Koda a gbo pe Gomina ipinlẹ Nassarawa ati ti Niger lawọn eeyan gba fọọmu fun.

Afẹnifẹre ni Atiku se fọkan tan lẹni ti yoo mu atunto ba eto iṣejọba Naijiria.

Saaju ko to busẹkun nibi to ti gba fọọmu ìfèróngbà rẹ ni igbakeji Aarẹ nigba kan ri lorileede Naijiria,Atiku Abubakar, ti se abẹwo si awọn olori ẹgbẹ Afẹnifẹre to jẹ ẹgbẹ awọn ọmọ Yoruba.

Oríṣun àwòrán, Dele Momodu

Àkọlé àwòrán,

Ọrọ atunto eto iṣejọba jẹ ohun ti o ti gba iwaju ọrọ oṣelu lorilẹede Naijiria

Oloye Ayọ Adebanjọ nibi ipade naa sọ pe awọn kan sara sii Atiku Abubakar pe eeyan ti awọn lee fi ọwọ rẹ sọya pe yoo ṣe ifẹ awọn Yoruba lori atunto eto iṣejọba lorilẹede Naijiria.

Igbakeji Aarẹ Yemi Osinbajo ko jẹ ki ọrọ na bale ki o to fẹsi pada lori bi Atiku ti se n polongo ọrọ atunto eto iṣejọba lorilẹede Naijiria.

Nigba ti Atiku naa ko gbe ẹnu rẹ fun alagbafọ, nise ni o da esi pada fun igbakeji Aarẹ Osinabjo

Ọrọ naa ko ti tan nilẹ

Ọ̀rọ́ PVC di kátàkárà, ará ìlú ń san tó N7,000

Ọjọ́ kọkanlelọgbọn, oṣù kẹjọ ní Àjọ eleto ìdìbò INEC kéde gẹgẹ bí gbendeke fún gbígba káàdì ìdìbò PVC.

Ọjọ́ yi gan si ni Aarẹ Buhari gbera kuro nile lọ si orileede China.

O daju wi pe baalu rẹ ko ti le gunlẹ si China ti awọn ọmọ Naijiria fi n ke irọra lori ai ri kaadi idibo PVC gba ti awọn kan si so ninu ifọrọwanilnuwo pẹlu BBC Yoruba pe awọn kan n gba ẹgbẹrun meje Naira lọwọ awn eeyan ki wọnn to le gba kaadi.

fidio ifọrọwanilẹnuwo naa ree

Àkọlé fídíò,

PVC: Ṣé a ṣẹ̀ 'jọba la ṣe ń jìyà lóri káádì ìdìbò ni?

Nitori akoko, awn isele miran rẹ eleyi ti ẹ le ri ka loju opo BBC Yoruba.

Igba ti Buhari lọ China ni gbogbo won naa sẹlẹ