Bobrisky: Wọn parọ́ mọ́ mi pé mo fẹ́ lọ ṣiṣẹ́ n'Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì

Bobrisky ti orukọ rẹ gangan n jẹ Idris Okuneye

Oríṣun àwòrán, Vanguard

Àkọlé àwòrán,

Bobrisky ni funra oun ni oun pada wa sile

Arakunrin ko-ṣ'ọkunrin-ko-ṣ'obinrin ti awọn ololufẹ rẹ mọ si Bobrisky ni idi ti wọn fi da oun pada lati Ilẹ Gẹẹsi ni pe eniyan kan lọ ṣe ofofo fun awọn ẹṣọ aṣọbode nigba ti oun balẹ si ilu ọba pe, ọja loun wa ta ni orilẹede naa.

O ni tori bẹẹ ni wọn ṣe da oun pada sile pe ki oun lọ gba iwe ìrìnna to tọ.

Ori Instagram lo ti ṣalaye ọrọ yii nigba ti iroyin jade pe wọn ti le wale lati Ilẹ Gẹẹsi to lọ ni ọjọ Eti.

Àkọlé fídíò,

'Wiwa ọkọ Baalu da bi ki ẹ lọ da duro sori apata'

Àkọlé fídíò,

'Ìgbà mẹẹ̀dógún ni mo ti ṣẹ́ oyún'

Bobrisky ti orukọ rẹ gangan n jẹ Idris Okuneye ni funra oun ni oun pada wa sile jẹjẹ nigba ti wọn rọ oun lati lọ gba iwe naa.

O ni, "Mo lọ Ilẹ Gẹẹsi lati lọ simi ni. Mo n pa to miliọnu kan naira l'ọṣu ni orilẹede Naijiria. Mo di olokiki ni orilẹede Naijiria, kilode ti n ko fi ni fẹran orilẹede mi? Awọn ẹṣọ ibode Ilẹ Gẹẹsi ṣe daadaa si mi."