'Ilé ìwòsàn ṣi abẹ́rẹ́ Formalin gún mí; n kò lè dá ìgbẹ́ àti ìtọ̀ dúró mọ́'

Ọ̀rọ̀ ọmọ bíbí ni mo bá dé ilé ìwòsàn ìjọba kí wọn tó ṣi abẹ́rẹ́ gún mi.

Iṣẹ́ abẹ oyún ìju (Fibroid) ni Christianah Ohunya ba lọ sile iwosan ijọba ni Orile Agege nipinlẹ Eko.

O ṣalaye fún BBC Yorùbá pé lẹ́yìn to wọle ọkọ lọdun mẹrin ti ko bimọ ni wọn ni ki oun wa ṣe iṣẹ abẹ latii yọ oyun ìju ti o n yọ oun lẹnu.

O ni dipo oogun orun ṣaaju iṣẹ abẹ ni wọn ba ṣe aṣiṣe gun oun labẹrẹ Formalin ti wọn maa n fun òkú ko ma baa bàjẹ́.

Nigba to n fesi lori alaye arabinrin Christiana naa, Kọmisana feto ilera nipinlẹ Eko, Ọgbẹni Jide Idris ni Christiana lẹtọ lati mọ̀ohun to n sẹlẹ sii.

Idris ni, ni kete ti isẹlẹ naa waye, nijọba ti pasẹ fawọn eeyan ti aje ọrọ naa si mọ lọwọ, lati lọ rọọ kun nile na, ki wọn maa baa dena iwadi ijọba lori ọrọ naa.

"A ti fi diẹ lara ohun ti wọn lo ransẹ si ibudo ayẹwo, taa si n reti abajade esi rẹ bayii. Ni kete ti esi ba si jade, laa fun ni itọju to yẹ."

Idris tun fọwọ gbaya pe ijọba ko ni dọwọ bo isẹlẹ yii, ti wọn yoo si tun tọju Christiana bo se yẹ.