'Mò ń fi Orin mi kọ́ àwọn èwe ní ẹ̀kọ́ ìwà rere'
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Tẹniọla: Pè mí láago tí o bá mọ iyán gún pẹ̀lú ọbẹ̀ ilá tó dùn

Ẹni tó ba ti wà láyé gbọ́dọ̀ kọ́ bi a ti ń mú inú ara ẹni dùn.

Tẹniọla Apata to jẹ gbajugbaja onkọrin ṣalaye fun BBC Yorùbá pé oun n tọ ipa ẹsẹ Niniọla ẹgbọn oun ni ninu orin kikọ.

O mẹnuba ẹkọ nla ti oun kọ́ lẹyin ikú baba òun pé kò si nkan ti a máa mú kúrò laye nigba ti ọlọ́jọ́ ba ti dé.

Alaṣe Tẹni Entertainment gba àwọn ololufẹ rẹ nimọran lati ṣọra fún ohunkohun to ba ti mu wahala dání nitori pe ọ̀rọ̀ ilé ayé yii kò tóo pọ́n rara.