Ọmọdé tó ń fi ọpọ́n àyò gba ipò
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ọpọ́n ayò: Àwọn ẹ̀yà mìíràn tó ń ta ayò alọ́pọ́n

Ayò ọlọ́pọ́n jẹ́ ọ̀kan lára àwọn eré ìdárayá tó ti pẹ́jù ní Nàìjíríà.

Lóòtọ́ ni ayò ọlọ́pọ́n jẹ́ gbajú-gbajà nílẹ̀ Yorùbá, ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀yà mì nàá ní ayò yíì.

Àwọn ẹ̀yà Edo n pè é ní Ise, àwọn ẹ̀yà Twi ní orílẹ̀èdè Ghana n pè é ní Oware. Bákan nàá ni àwọn ẹ̀yà ìgbò n pé è ní Nchorokoto/Nch?Okwe.

Ẹ̀wẹ̀, àwọn eré ìdárayá kan wà ní àwọn orílẹ̀èdè mì í nílẹ̀ Afrika tó fi ara jọ ayò ọlọ́pọ́n. Lára wọn ni eré ìdárayá Endodoi tó wọ́ps láàrin àwọn ènìyàn ẹ̀yà Maasai l'órílẹ̀èdè Kenya àti Tanzania.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ sí:

'Ọpọ́n ayò títa ti di ìdíje ńlá ni Abẹokuta' Ṣé o láyà?

Ìpàdé ìtagbangba ní Ọṣun, ṣẹ́ ti fi orúkọ sílẹ̀ ?

‘PDP kò mọ̀ nìpa Femi Otedola tó ń dupò gomina’

Ní ayé àtijọ́, abẹ́ igi tàbí abẹ́ àtíbába ni wọ́n ti máà ta ayò ọlapọ́n. Ọwọ́ ìrọ̀lẹ́ lẹ́yìn iṣẹ́ ni wọ́n sì màá n ta á.

Ọpọ́n àyo nàá máà n ní ihò méjìlá, mẹ́fa ní abala kọ̀ọ́kan. Ọmọ ayò méjìdínlógójì ní wọ́n fi máà n ta á. Ọmọ ayò mẹ́rìn nínú ihò kọ̀ọ́kan.

Ènìyàn méjì ló maa n ta ayò lẹ́ẹ̀kan nàá, ọ̀kọ́ọ̀kan wọn ló sì ni ihò tó wà nínú ọpọ́n ayò.

Ẹnì kọ̀ọ́kan wọn yóò máà kó ọmọ ayò kúrò nínú ihò kan sí òmí. Lọ́gán ọ̀kan lára àwọn tó n ta ayò kó bá rí ibi kó ọmọ ayò rẹ̀ sí mọ́ ni eré parí.

Tí ẹnìkan bá kọjá bá wọn níbi tí wọ́n ti n tayò yíì, yóò kí wọn pé ''Mo kí ọ̀ta, mo kí òpé.''

Àwọn tó n tayò, pàápàá, ẹni tó jáwé olúborí yóò sì dáhùn pé "ọ̀ta n jẹ́, òpè ni kò gbọdọ̀ f'ọhùn."

Ẹni tó n jáwé olúborí ni ọ̀ta.

Ní báyìí, ayò ọlọ́pan ti wà lórí ẹ̀rọ ìbáraẹni sọ̀rọ̀ alágbèéká.