Kí ló kan Burẹ́dì Agége pẹ̀lú epo Diesel?

Bí owó burẹdi ṣe gbowo lori si

O ṣeéṣe kí ẹ̀kúnwó ba ìyè tí wọn n ta Burẹdi jakejado Nàìjíríà.

Ẹgbẹ́ àwọn tó ń ṣe búrẹ́dì lórílẹ̀èdè Nàìjíríà sọ pé ohun tó fa sábàbí èyí ni bí owó àwọn èròjà tí wọ́n fi ń ṣe bùrẹ́dì ṣe wọ́n àti ìdá mẹ́tàdínlọ́gọ́ta tó kún ọ̀wọ́ngógó epo diesel.

Ààrẹ ẹgbẹ́ àwọn tó ń ṣe búrẹ́dì lórílẹ̀èdè Nàìjíríà, Jemide Tosan sọ fún àwọn oníròyìn pé bí owó ṣe gorí àwọn èròjà tí wọ́n fi ń ṣe bùrẹ́dì ń dí àwọn tó ń tà á lọ́wọ́.

Ọ̀gbẹ́ni Tosan jẹ́ kó di mímọ̀ pé láàrin ọdún 2015 sí 2018, owó ìyẹfún ti gòkè láti ẹgbẹ́rún mẹ́fà àbọ̀ Náírà sí ẹgbẹ́rún mọ́kànlá àbọ̀ Náírà fún báàgì 50kg nígbà tí owó ṣúga, yístì àti ọ̀rá náà ti gbówó l'órí.