PDP: APC ń lo EFCC láti halẹ̀ mọ́ ẹbí Adeleke

Davido Image copyright @iam_Davido
Àkọlé àwòrán EFCC ko tii sọrọ lori iroyin yii

Gbajugbaja olorin nni Davido, ti ké gbàjarè síta pé ajọ to n gbogun ti iwa ijẹkujẹ lorilẹede Naijiria, EFCC ti gbẹsẹ le aṣuwọn owo òun.

Amọṣa o, kii ṣe aṣuwọn rẹ nikan ni wọn gbẹsẹ le bi ko ṣe pẹlu ti aburo baba rẹ Ademọla Adeleke to n du ipo gomina labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ọṣun.

Image copyright @IsiakaAdeleke1
Àkọlé àwòrán Senator Isiaka Ademola Adeleke

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

PDP pè fún fífi Kemi Adeosun jófin

APC àti PDP takora wọn lórí Olùsirò owó àgba Ọsun tó fisẹ́ sílẹ̀

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBọla Tinubu: Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun kò ní owó mi lọ́wọ́

Bakan naa ni iroyin sọ pe wọn tun gbẹsẹ le aṣuwọn Deji Adeleke to jẹ baba Davido, to si tun jẹ ilumọọka oniṣowo.

Ohun ti ẹgbẹ oṣelu PDP n sọ

Ninu atẹjade kan to fi sita lori ikanni twitter rẹ, gbajugbaja olorin taka sufe naa ti ọpọlọpọ mọ si ọmọ baba olowo ti sọ pe, bi o ti wulẹ o ri, omimi kan ko lee tori eyi mi atilẹyin oun fun aburo baba oun lati di gomina nipinlẹ Ọṣun nitori ọmọ ẹni ko le ṣedi bẹbẹrẹ ka sin ilẹkẹ si idi ọmọ ẹlomiran.

Image copyright @iam_Davido
Àkọlé àwòrán Ẹgbẹ oṣelu PDP wa ke si aarẹ lati wa nnkan ṣe si ọrọ naa

Amọṣa ẹgbẹ oṣelu PDP ti pariwo sita pe ki aarẹ Muhammadu Buhari o tete ke si ajọ EFCC pe ko da gbe ẹsẹ kuro lori aṣuwọn owo Adeleke ninu eyi ti Sẹnetọ Ademọla Adeleke to n dije gẹgẹ bii oludije ẹgbẹ oṣelu naa nibi idibo gomina ti yoo waye lọjọ kejilelogun oṣu kẹsan.

Ninu atẹjade kan, ẹgbẹ oṣelu PDP ni igbesẹ naa lasiko ti eto idibo gomina nipinlẹ Ọṣun ku ọsẹ kan jẹ iwa idunmọhurumọhuru mọ alatako ati eyi to lee da họwu-họwu silẹ nipinlẹ naa.