'Ẹgba jíjẹ máa ń dùn mọ́ wa ni ọdún ìjẹṣu Ilaramọkin ni Ondo'
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

'A máa ń bẹ́ orí ẹni tó bá gbé imọlẹ̀ ọdún ìjẹṣu tó bá ṣubú ni'

Ìrọ̀rùn ni ẹgba jíjẹ ba dé ni ọdún ijẹṣu Ilara-mọkin nipinlẹ Ondo.

Bi ọmọ kò bá ba ìtàn; ó máa n ba àrọ́bá ni, ọdún ìjẹṣu Ilara-mọkin kò déédé bẹ̀rẹ̀.

Oba Abiọdun Aderẹmi Adefẹhinti sọ ohun to ṣokunfa àṣà ẹgba nínà lásìkò ọdún ìjẹṣu.

Alara ti Ilara-mọkin to jẹ Agbekọrun II sọrọ lori awọn ayipada to ti de ba ọna ṣiṣe ọdun Òbèrèmóyè.

Awọn èèkàn nibi ọdun ijẹṣu naa ṣalaye fun BBC Yoruba lori igbesẹ ọdun naa àti àwọn èèwọ̀ inu rẹ̀ bii bíbẹ́ orí fun ọlọsin to ba gbe imọlẹ to ba ṣubu lasiko ti imọlẹ naa ṣì wà lọwọ rẹ̀.

Igbagbọ awọn eniyan Ilaramọkin ni pe ẹgba naa kìí pẹ́ pa ojú dé nitori omi ẹ̀rọ̀ ti wọn n wọn sí ojú ọgbẹ́ naa.

Wọn ni àwọn ọdọ lo maa n kopa julọ ninu ẹgba nínà náà.