2019 election: Jimi Agbaje yan ọmọ ọba Kosọkọ gẹ́gẹ́bí igbákejì rẹ̀

Haleemat Busari

Oríṣun àwòrán, Jimi Agbaje

Àkọlé àwòrán,

Ọmọọba Kosọkọ nisalẹ Eko ni Jimi Agbaje yan gẹgẹbi igbakeji rẹ

Oludije fun ipo gomina labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Eko, Jimi Agbaje ti yan arabnrin Haleemat Busari gẹgẹ bii oludije funigbakeji rẹ.

Ninu atẹjade kan to fi sita ni ọjọbọ, ọgbẹni Agbaje ni oun yan arabinrin Busari lẹyin ọpọlọpọ ijiroro pẹlawọn aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu naa.

Igbakeji rẹ yii wa lati idi ọba kosoko ni isalẹ Eko.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọgbẹni Agbaje ni ọpọ ni ireti pe yoo jẹ olufigagbaga pẹlu ọgbẹni Sanwo-olu ti ẹgbẹ oṣelu APC lasiko idibo fun ipo gomina nipinlẹ Eko.

Ninu ọrọ to fi sita lori ikani tweeter rẹ, arabinrin Busari ni inu oun dun lati gba ipe tuntun yii nitori, 'ko si ipe to ga ju ipe lati sin Ọlọrun, awọn eeyan ati orilẹede lọ'

Jimi Agbaje ni yóò dupò gómìnà f'ẹ́gbẹ́ PDP nipinlẹ Eko

Oríṣun àwòrán, Facebook/Jimi Agbaje

Àkọlé àwòrán,

Jimi Agbaje ni ìbò 1100 kó tó borí Doherty tó ní 742

Jimi Agbaje ni yoo dije fun ipo gomina nipinlẹ Eko labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP ninu idibo ọdun 2019 lẹyin to jawe olubori ninu ibo abẹle ti wọn ṣe.

Agbaje ni ibo ọgọrun le ni ẹgbẹrun kan nigba ti alatako rẹ Adedeji Doherty si ni ibo oji le lẹẹdẹgbẹrin o le meji.

Agbaje dije fun ipo gomina ni Ipinlẹ Eko ninu idibo ọdun 2015 ṣugbọn o fidi rẹmi nigba ti Gomina Akinwunmi Ambode jawe olubori ninu idibo ọhun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Wọnyi ni awọn to dije fun ipò gómìnà lábẹ́ àsìá ẹgbẹ́ nàá nínú ìbò gómìnà l'ọ́dún 2019,

Oríṣun àwòrán, @OfficialPDPNig

Abia: Okezie Ikpeazu

Adamawa: Alhaji Ahmadu Fintiri

Akwa Ibom: Udom Emmanuel

Bauchi: Sẹnet Bala Mohammed

Cross Rivers: Ben Ayade

Delta: Ifeanyi Okowa

Ebonyi: David Umahi

Enugu: Ifeanyi Ugwanyi

Kaduna: Isa Ashiru Kudan

Nasarawa: David Ombugadu

Niger: Umar Nasko

Ogun: Ladi Adebutu Lado

Oyo: Seyi Makinde

Plateau: Jeremiah Useni

Rivers: Nyesom Wike

Sokoto: Alhaji Manir Dan-Iya

Taraba: Darius Ishaku

Katsina: Lado dan Maeke

Jigawa: Malam Aminu ibrahim Ringim

Kebbi: Issah Galaudi

Kwara: Rasaq Atunwa

Atunwa ni olùdíje PDP fún ipò gómínà ní Kwara

Àkọlé àwòrán,

Wan ni kí alága APC ní Ìpínlẹ̀ Kwara lọ rọ́ kún ńlé

Razak Atunwa lo jawe olu bori ninu idibo abẹle PDP ni Ipinlẹ Kwara. Idibo naa ni ẹgbẹ oṣelu naa fi yan ẹni ti yoo gbe asia ẹgbẹ naa ni ọdun 2019.

Ibo ẹgbẹrun le ni ọgọrun ni o ni.

Ṣaaji, minisita fun ere idaraya Bolaji Abdullahi to jẹ agbẹnusọ ẹgbẹ oṣelu APC nigba kan ri yọwọ ninu idije naa.

Abdullahi wa lara awọn mẹjọ ti wọn ni awọn ko dije mọ, eyi to fi ku aṣofin Atunwa ati Sha'aba Lafiagi.

Oríṣun àwòrán, Bolaji Abdullahi/Facebook

Àkọlé àwòrán,

Oludije to ni oun ṣetan lati sin Kwara

Ni kete to kuro ni ẹgbẹ APC ni o fi han wipe oun yoo dije dupo gomina l'abẹ ẹgbẹ oṣelu PDP.

ṣe n lọ l'áwọn ìpínlẹ̀:

Ipinlẹ Ọyọ

Ìbò 2772 ni Ṣeyi Makinde ni nibi idibo abẹle naa nigba ti Senetọ Ayọade Adeṣeun ti wọn jọ dije ni ìbò 21 ti wọn si wọgile ibo 141.

Makinde ṣeleri pé oun yoo ṣatun'ṣe sigbe ayé awọn ara ìpínlẹ̀ Ọyọ ti oun ba le wọle sipo gomina ipinlẹ Ọyọ.

Ìpínlẹ̀ Abia

Gomina Ipinlẹ Abia to wa lori aleefa lọwọ Okezie Ikpeazu ni wọn dibo yan gẹgẹ bi oludije fun ipo lẹgbẹ oṣelu PDP ninu ibo abẹle to waye lọjọ Aiku nilu Umuhaia.

Àkọlé àwòrán,

Ni papa iṣre Umuhaiha ni wọn ti dibo yan gomia Okezie Ikpeazu láti dije fun ipo gomina lẹgbẹ oṣelu PDP

Ibo 1991 ni Ikpeazu ni lati jawe olubori ninu idibo abẹle ọhun.

Raymond Dokpesi to mojuto eto idibo naa bọwọ pẹlu gomina Okezie Ikpeazu lẹyin ti wọn kede rẹ tan gẹgẹ oludije fun ipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP.

Àkọlé àwòrán,

Okezie Ikpeazu ati Raymond Dokpesi bọwọ nibi idibo abẹle PDP nilu Umuhaia.

Ipinlẹ Bauchi:

Awọn oludibo naa ti jade sita nibudo idibo nipinlẹ Bauchi ṣugbon wọn ko tii bẹrẹ idibo abẹle naa lati yan oludije ti wọn fẹ.

Àkọlé àwòrán,

Ki awon ohun eelo idibo de naa ni awọn oludibo PDP n duro de ni Bauchi

PDP sún ìbò abẹ́lé síwájú ni Kano, Imo ati ipinlẹ Eko

Ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò gbòógì ní Nàìjíríà, Peoples Democratic Party, PDP, ti sún ètò ìdìbò abẹ́lé ẹgbẹ́ nàá síwájú ní àwọn ìpínlẹ̀ kan.

Ṣàáju ni ẹgbẹ́ nàá ti kéde ọgbọ̀njọ́, oṣù Kẹsàn án, gẹ́gẹ́ bi ọjọ́ tí wọn yóò dìbò yan àwọn tí yóò díje dupò gómìnà lábẹ́ àsìá gbẹ́ nàá nínú ètò ìdìbò gbogboogbò tí yóò wáyé l'ọ́dún 2019.

Eto idibo abẹlẹ wọn yoo waye lawọn ipinlẹ to ku lonii yatọ si ipinlẹ Eko, Imo ati Kano ti wọn sun siwaju.

Oríṣun àwòrán, @OfficialPDPNig

Àkọlé fídíò,

Ọlọ́jọ́2018: Àwọn kan ní gbogbo àgbáyé ló ni ọdun Ọlọ́jọ́, kìí se Ifẹ̀ nìkan

Alukoro ẹgbẹ́ nàá, Kọla Ologbondiyan sọ fún BBC pé ẹgbẹ́ ti sún ètò ìdìbò abẹ́lé síwájú ní ìpínlẹ̀ Eko, Imo àti Kano, láti le fún ẹgbẹ́ ní ànfàání láti ṣe ìjíròrò tó dára láàrin ara wọn.

Ó ní bi ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò tìí mọ ọjọ tí ètò ìdìbò nàá yóò wáyé, Ologbondiyan sọ pé ohun tó dájú ni pé ẹgbẹ́ PDP yóò ṣe ètò ìdìbò abẹ́lé ní àwọn ìpínlẹ̀ nàá kó tó di gbèdéke ọjọ́ karùn ún, oṣù Kẹwàá, ti àjọ elétò ìdìbò ní Nàìjíríà, INEC, fún àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú láti sẹ bẹ̀.

Ta ni alaga ẹgbẹ PDP tuntun fun ipinlẹ Eko?

Lórí ìròyìn kan to jáde pé ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP, ti fi ẹlòmíì rọ́pò alága ẹgbẹ́ nàá ní ìpínlẹ̀ Eko, Kọla Ologbondiyan, sọ pé lóòtọ́ ni ìgbésẹ̀ n lọ láti pàárọ̀ alága ẹgbẹ́ PDP ní Eko, ṣùgbọn wọn kò tí ì kéde ẹnikẹ́ni gẹ́gẹ́ bi alága tuntun.

Ọjọ́ Àìkú, ọgbọ̀njọ́ oṣù Kẹ́sàn án ni ètò ìdìbò abẹ́lé gbẹ́ PDP yòó wáyé ní àwọn ìpínlẹ̀ tó kù jákè-jádò orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.