Ọmọ Nàìjíríà tó fẹ́ pa adájọ́ lọ ẹ̀wọ̀n gbére ní Amẹ́ríkà

Omo Naijiria Chimene Onyeri Image copyright Olopaa Texas
Àkọlé àwòrán Ile ẹjọ ni Onyeri yoo lo iyoku aye rẹ ni ẹwọn

Ọmọ Naijiria ẹni ọdun mọkanlelogun kan Chimene Onyeri ti rẹwọn he ni orilẹede Amerika lẹyin fun ẹsun jibiti, if'ọgbọn gbowo eru ati pe o gbiyanju lati yinbọn pa adajọ kan ti orukọ rẹ n jẹ Julie Kocurek ni ọdun 2015.

Nibi idajọ Onyeri ni ile ẹjọ ijọba apapọ kan ni ilu Austin, Ipinlẹ Texax, adajọ Lee Yeakel ni arakunrin naa yoo lo iyoku aye rẹ ni ẹwọn. O si tun paṣẹ fun pe ki ẹlẹwọn naa ko san owo itanran to le ni ẹgbẹrun lọna mejidinlọgọsan dọla fun ẹsun jibiti rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ sí:

Oṣu kẹrin ọdun 2018 ni ile ẹjọ da Onyeri lẹbi fun gbogbo awọn ẹsun rẹ. Adajọ Kocurek ti arakunrin naa gbiyanju lati yinbọn pa ni inu oun dun pe ọrọ naa to ti wa nile ẹjọ fun ọdun meji ati oṣu mọkanla ti wa pari bayi ati wi pe idile oun ko ni lati maa bẹru oun ti Onyeri ati awọn akẹgbẹ rẹ yoo ṣe fun awọn mọ.

Àkọlé àwòrán Agbẹjọro rẹ ni irẹwẹsi ọkan de ba Onyeri fun oun to ṣẹlẹ si adajọ Kocurek

Iroyin ni aaye wa fun Onyeri lati lọ ile ẹjọ kotẹmilọrun. Agbẹjọro rẹ ni irẹwẹsi ọkan de ba Onyeri fun oun to ṣẹlẹ si adajọ Kocurek. Agbẹjọro naa gbiyanju lati ge ẹjọ ti wọn da fun Onyeri si ọgbọn ọdun l'ẹwọn.

Awọn mẹwaa miiran ti wọn jọ mu ni wọn n duro fun idajọ bayii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionỌ̀rọ̀ Trump àti Russia kò yàtọ̀ pé àhesọ lásán ni èyí jẹ́