'Kò wu èmi náà kí ń má ládé orí ṣùgbọ́n...'
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Àwa obìnrin tó ń lépa afòjúsùn máa n ba ọkùnrin lẹ́rù ni -Toyin Lawani

Ọmọ ọdún mejidinlogun ni mii tí mo fi bẹ̀rẹ̀ òwò yìí.

Gbajugbaja aṣaraloge, Toyin Lawani, bá BBC Yorùbá sọ̀rọ̀ lóri ìgbé ayé lọ́kọ-láya pé ọpọ ìgba ni kii wu obinrin lati kọ ọkọ rẹ̀ silẹ ṣugbọn ti iriri onikaluku ko faaye silẹ fun un lati tẹsiwaju.

O gba pe, igbe aye tọkọtiyawo dùn ṣugbọn ó máa ń kan nigba mii.

Toyin ni o yẹ ki a gbóṣùbà fawọn obinrin ti wọn kò si nile ọkọ ṣugbọn ti wọn n tiraka lati tọju awọn ọmọ wọn daadaa ni.

O ṣalaye fún BBC pe nitootọ loun ti jẹ aya lọọdẹ ọkunrin meji ri ṣugbọn kii ṣe ìfẹ́ inu oun lati di alailade lori.

Toyin fun awọn obinrin nimọran kikun lori bi wọn ṣe le di olokowo nla nipa ṣiṣe iwadii, mimọ oun too fẹ ṣe, titun ara rẹ ṣe daadaa nitori irinisi nisọnilọjọ ni Yoruba maa n wi.

O gbawọn ọkunrin nimọrin lati maa ṣatilẹyin fun iyawo wọn ti wọn ba jẹ ọkọ daadaa.

Bakan naa lo ṣe lodi si gbigbe igbesi aye rẹ sori ayelujara nitori kii jẹ ki ibadọrẹ pẹ́ ti aye ba ti mọ nipa rẹ ati pe ohun ti a ba fipamọ lo maa n níyì.