Buhari : Mi ò faramọ́ èrò APC lórí àwọn tó ń bínú

Àwòrán ẹgbẹ́ APC

Oríṣun àwòrán, Twitter/APC

Àkọlé àwòrán,

Àìfìmọ̀sọ̀kan ló ń da ẹgbẹ́ APC rú ní Ìpínlẹ̀ Zamfara

Aarẹ Orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ti sọ wi pe, ohun ko faramọ asẹ ẹgbẹ oselu APC to ni ki awọn ti inu ba n bi ko gbọdọ lo si ile-ẹjọ.

Aarẹ Buhari fi eyi lede lori ẹrọ ikansiraẹni, Twitter rẹ lẹyin ti Alaga apapọ ẹgbẹ oselu APC, Adams Oshiomole kilọ fawọn ọmọ ẹgbẹ to n binu lati fagile bi wọn se n gbe ẹgbẹ oselu APC lọ si ile-ẹjọ.

Aarẹ Buhari sọ pe, ẹtọ ọmọ eniyan ni lati lọ si ile ẹjọ ti o ba ri wi pe nkan ti wọn se fun oun ko tẹ oun lọrun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Jide Kosọkọ: Isẹ́ tíátà yóò gòkè tíjọba bá gbówó kalẹ̀ láti seré

O fikun wi pe, ẹgbẹ oselu APC parapọ wi pe ki idibo abẹlẹ waye ni ọna ti o ba ofin mu, sugbọn ti ẹnikan ba wi pe wọn se ohun ti ko tọ si oun lasiko naa, le lọ si ile ẹjọ.

Aarẹ orilẹede Naijria fikun wi pe, ile ẹjọ wa fun awọn mẹkunu lati fi ẹhonu wọn han lai si idiwọ lati ọdọ awọn adari.

'Àìfìmọ̀sọ̀kan ló ń da ẹgbẹ́ APC rú ní Ìpínlẹ̀ Zamfara'

Àkọlé àwòrán,

Àìfìmọ̀sọ̀kan ló ń da ẹgbẹ́ APC rú ní Ìpínlẹ̀ Zamfara

Alaga ẹgbẹ oṣelu APC Adams Oshiomole ti gbena woju Ajọ to n ri si Eto Idibo Ipinlẹ Zamfara lọdun 2019.

Ajọ to n ri si eto idibo lorilẹede Naijiria INEC ti kọkọ kede pe awọn ti f'ofin de ẹgbẹ oṣelu APC pe awọn oludije fun ipo kan tabi omiiran ko ni lanfani lati kopa ninu idibo ọdun to n bọ nitori iwa iwọ o ju mi emi o ju ọ laarin awọn alaṣẹ ẹgbẹ oselu APC nipinlẹ Zamfara.

Idi abajọ ni aifimọsọkan laarin awọn adari ẹgbẹ naa ati ijọba Ipinlẹ Zamfara lati ṣe idibo abẹle ko to di Ọjọ Keje, Oṣu Kẹwa gẹgẹ bi gbedeke ti Ajọ INEC fi lelẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Sugbọn Oshiomole fariga o ni ẹgbẹ APC yoo kopa ninu idibo ọdun ti o n bọ.

Ninu iwe ti ajọ INEC kọ ranṣẹ si ẹgbẹ APC, adele fun akọwe ajọ naa Okechukwu Ndeche sọ pe igbesẹ naa wa ni ibamu pẹlu ilana eto idibo gẹgẹ bi o ti wa ninu iwe ofin Naijiria.

Iroyin to n tẹ wa lọwọ sọ pe ohun to fa ija ni pe Gomina Ipinlẹ Zamfara Abdul Aziz Yari to fẹ dije fun ipo sẹnẹtọ fẹ ki kọmisọna eto isuna, Mukhtar Idris dije fun ipo gomina bẹẹni Sẹnetọ Kabiru Marafa fẹ dupo kan naa.

Ẹwẹ, aya ààrẹ Muhammadu Buhari ti APC ṣẹṣẹ yàn lati dije dupo aarẹ lọdun 2019 ké gbàjarè síta lóri ètò ìdìbò abẹ́lé ẹgbẹ oṣelu APC.

O ni bi wọn ṣe n fun awon kan niwe ẹri o pegede lati dije lai dibo naa ni wọn n kọ lati ṣeto idibo to yaranti fawọn oludije mii.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Aisha Buhari fẹsun kan ẹgbẹ oṣelu APC pé wọn kò ṣootọ tó

Aisha Buhari ni alaga ẹgbe APC ko ṣe ohun to yẹ tó lati mu ayipada rere ba eto iṣejọba alagbada pẹlu ohun to n ṣelẹ ni APC bayii.

Bakan naa lo fi sori ikanni ayelujara ti instagram rẹ pe asiko ti tó ki awọn oludibo kọ iwa tani-o-mumi to n ṣẹlẹ lọwọ ni APC ki wọn le yan awọn oludije to wu won sipo.

Nigba ti BBC kan si Garba Shehu to jẹ oluranlọwọ pataki fun Aarẹ Buhari lori iroyin, ko gbe aago rẹ bẹẹ ni ko fesi si atẹran'se ti a fi ranṣẹ sii titi di asiko ti iroyin yi fi jade.

Àkọlé fídíò,

APC Primaries: A ṣi n lọ sílé ẹjọ́ lóṣù tó m bọ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí

Àkọlé fídíò,

APC Primaries: 'Kò sí 'Faction' ni Kwara APC rárá, NWC ti sọ̀rọ̀'

Àkọlé fídíò,

Ọmọ̀bìnrin tí wọ̀n bí láì ní ẹsẹ̀: Ati kekere ni ìyá mí ti kọ̀mí sílẹ̀

Àkọlé fídíò,

Obinrin lo mu mi fẹran orin kikọ - Patoranking