Presidency 2019: Oby Ezekwesili yan Galadima alága ACPN gẹ́gẹ́ bíi igbákejì rẹ̀

Oby Ezekwesili

Oríṣun àwòrán, @SHEWENZI

Àkọlé àwòrán,

Ezekwesili tó jẹ́ ọ̀kan lára olùdásílẹ̀ ẹgbẹ́ Bring Back our Girls #BBOG ní ẹni tó mọ̀ nípa mẹ̀kúnù ni òun yàn ní igbákejì.

Oludije fun ipo aarẹ orilẹede Naijiria labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu Allied Congress Party of Nigeria, ACPN, Ọmọwe Oby Ezekwesili ti yan alaga apapọ ẹgbẹ oṣelu naa, Ganiyu Galadima gẹgẹ bii igbakeji rẹ ninu idibo sipo aarẹ Naijiria ti yoo waye ni ọdun 2019.

Oby Ezekwesili ni awọn iṣẹ takuntakun ti Galadima ti ṣe lori ọrọ idagbasoke igberiko lo mu ki oun yan an.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bakan naa lo ṣalaye pe igbakeji oun yoo lee kun oun lọwọ lati di oloṣelu to pe, yoo si tun duro gẹgẹ bii alabasowọpọ fun awọn amuyẹ oun pẹlu.

"Eniyan mimọ ni Alhaji Abdulganiyu Galadima fun iṣẹ ti o ti ṣe ni igberiko ati ẹsẹ kuku. Gẹgẹ bii eeyan to ti ṣiṣẹ de ibi ere ni ijọba ibilẹ, iru eeyan bii rẹ ni mo nilo, fun wa lati gbe ọgọrin miliọnu awọn eeyan kuro ninu iṣẹ."

Oby Ezekwesili: Mò ń dupò ààrẹ gẹ́gẹ́ bí ará ìlú

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán,

Mínísítà fún ètò ẹ̀kọ́ tẹ́lẹ̀ rí tó tún jẹ́ ọ̀kan lára olùdásílẹ̀ ẹgbẹ́ Bring Back our Girls #BBOG Oby Ezekwesil náà kéde láti dupò ààrẹ Nàìjíríà.

Ọ̀kan lára olùdásílẹ̀ ẹgbẹ́ ajafẹtọ ọmọniyan, Bring Back our Girls, #BBOG, Oby Ezekwesil náà ti kéde láti dupò ààrẹ Nàìjíríà ní ọdún 2019.

Nínú àtẹ̀jáde kan, Abilekọ Ezekwezili sọ wi pe awọn ẹgbẹ oselu mejeeji to ti se ijọba ri jẹ obayejẹ, eleyi to fi mu ohun lati sọ wi pe ohun fẹ dije dupo aarẹ lọdun 2019.

Arabinrin naa jẹ gbajugbaja ti awọn eniyan mọ si ajafẹtọ ọmọniyan to ja fitafita fun ominira awọn ọmọbinrin Chibok ti awọn ajinigbe Boko Haram jigbe lọdun 2014.

Àkọlé àwòrán,

Ọpọlọpọ obinrin lo ti gbiyanju lati dije dupo aarẹ lorilẹede Naijiria tẹlẹri, amọ Ezekwezili lo jẹ obinrin to gbajumọ ju lati dije dupo aarẹ orilẹede Naijiria.

Ọpọlọpọ obinrin lo ti gbiyanju lati dije dupo aarẹ lorilẹede Naijiria tẹlẹri, amọ Ezekwezili lo jẹ obinrin to gbajumọ ju lati dije dupo aarẹ orilẹede Naijiria.