Ekiti: Àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin yọ abẹnugan ilé

Fayose ati Kolawole
Àkọlé àwòrán Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Ekiti yọ Abenugan rẹ̀

Àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ aṣòfin ìpínlẹ̀ Ekiti tí yẹ àga nídìí abẹnugan ilé ìgbìmọ Aṣofin ìpínlẹ̀ Ekiti, Kolawole Oluwawole àti igbákejì rẹ Ṣina Animasahun.

INEC: Èsì ìdìbò Ekiti lẹ́kùnrẹ́rẹ́

Ẹlẹka: Ìdá àádọ́rin nínú ọgọ́rùn ni mo ní nínú ìbò Ekiti

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption#EkitiDecides: 'Ìjà ẹgbẹ́ òkùnkùn ló ń ṣẹlẹ̀ kìí ṣe ti òṣèlú'
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKayode Fayemi : Awọn osisẹ ni Ekiti ko i tii gba owo osu ni ọdun yii

Bákan náà ní wọn ti yàn abẹnugan mìíràn, Adeniran Alagbada nígbà ti wọn tún igbákejì abẹnugan tí wọn ti gbọ̀n yọ tele Segun Adewunmi pada sípò gẹ́gẹ́ bíi igbákejì abẹnugan ilé.

Olorí ilé tuntun ti wọn yan bayìí ní olori ọmọ ilé tó kéré jùlọ tẹ́lẹ̀, Gboyega Aribisogan nígbà ti Sunday Akinniyi tí gbogbo ènìyàn mọ si 'Gbosa' bó tilẹ̀ jẹ́ pe ó ṣẹ̀ṣẹ̀ darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ APC ló wá jẹ́ olórí ọmọ ilé tó kéré jùlọ báyìí.

Ní bayìí wọn ti bura wọlé fún gbogbo wọn.

A ó máa mú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìròyìn náà wá fún un yín.