Àhámọ́ Leah àtàwọ́n ọmọbìnrin míì ṣì ń kọni lóminú

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionǸ jẹ́ ó wù yín kí gbogbo ọmọ tí ẹ bí jẹ obìnrin?

Oni ọjọ kọkanla oṣu kẹwa ọdun 2018 ni ayajọ ọjọ ọmọbinrin lagbaye.

Ajọ iṣokan agbaye U.N.O. lo ya ọjọ naa sọtọ lọdun 2012 lati jẹki awọn eeyan mọ awọn ipenija ti awọn ọmọbinrin n koju ninu eto ẹkọ, ounjẹ jijẹ, ati fifi ọmọdebinrin lọkọ.

Iwadii fi han pe awọn ọmọbinrin to wa lagbaye le diẹ ni biliọnu kan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Orilẹede Naijiria naa darapọ mọ gbogbo eeyan lagbaye lati sayẹyẹ ayajọ ọjọ ọmọbinrin.

Ọrọ pọ ninu iwe kọbọ lori ayajọ ọjọ ọmọbinrin lagbaye lori ayelujara Twitter.

Malala Yousafzai to jẹ ajafẹtọ ọmọbinrin, to si ti gba ami ẹyẹ Nobel Peace, sọrọ loju opo rẹ pe o ṣe pataki lati mu ra ọmọbinrin silẹ loni fun iṣẹ lọjọ ọla.

O fi kun ọrọ rẹ pe o tun ṣe koko lati din iyato to wa laarin owo oṣu ọkunrin ati obinrin ku lagbaye.

Akẹkọọbinrin kan ti orukọ rẹ n jẹ doyinsola sọ pe o ṣe pataki lati fun ọmọbinrin ni ẹkọ to ye kooro nitori eyi lo maa jẹki idagbasoke ba orilẹede lapapọ

O salaye pe oun fẹ lọ kẹkọ ni fasiti pẹlu erongba lati ṣe imoriwu fun awọn ọmọbinrin lagbaye.

Arabinrin Georgina Ndukwe ni oun nigbagbọ ninu awọn ọmọbinrin pe wọn lagbara lati yi aye pada si rere ti wọn ba fun wọn laaye.

Afolabi Olajide sọ pe o yẹ ki awọn eeyan maa bọwọ fun ọmọbinrin lawujọ, o ni o ṣe pataki lati ṣe itọju wọn daadaa.