RRS gbé ẹlẹ́wọ̀n lẹ́yìn ọjọ́ 5 tí wọn tú sílẹ̀ ní ọgbà ẹwọ̀n Ikòyí

Okunola àti Adigun Image copyright RRS
Àkọlé àwòrán Ọlọ́pàá tún ọ̀daràn mú lẹ́yìn ọjọ́ karún tó kurò lẹ́wọ̀n

Àwọn ẹka ọlọ́pàá RRS (Rapid Response Squad) tí ìpínlẹ̀ Eko tí tún ọdaran kan mú lẹ́yìn ọjọ́ marún-ùn tí tí ó gbà òmìnira kúrò ní ẹwọ̀n Ikoyi.

Afunra sí ọ̀hún Tunde Okunola ní wọn mú ní láyípo Marwa ní ìlú Lekki pẹ̀lú agbódegbà rẹ̀ Segun Adigun lásìkò tí wọn ń gbìyànjú ja Gift Omini lólè ní dédé ààgo márùn ku ìṣẹ̀jú méèdóógún ààrọ̀ lójọ́rú.

Okunola tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ kúrò lọ́gbà ẹ́wọ̀n Ikoyin lọ́jọ́ karún oṣù yìí gẹ́gẹ́ bí àtèjáde tí àjọ ọlọ́pàá fí sí ta ṣe sọ, sàlàyé pé Okunola tí lo oṣù mẹ́fà àti ọ̀sẹ̀ méjì lọ́gbà ẹ̀wọ̀n kí wọn tó túu sílẹ̀ sùgbọ̀n ọwọ́ àwọn agbófinró tí tún tẹ̀ẹ́ báyìí nígbà tó fẹ́ ja Gift Omini lólè fóónù láti orí òkadà.

Lásìkò tí ó ń bẹ àwọn ọlọ́pàá Okunola ní kí wọn síjú àànú wo òun nítori pé owó tí òun yóò fí ṣe ayẹyẹ ìkọ́ṣẹ́ parí fún iṣẹ́ bábà tí oun kọ́ ni àti pé tí wọn bá tú oun sílẹ̀, oun kò ní fi ẹsẹ̀ tẹ ìlú Ekó mọ.

Gift tí wọn gbìyàjú àti jà lólè sàlàyé pé wọn yọ ààké sí oun láti orí ọ̀kadà tí wọn wà sùgbọ́n ariwo tí oun pa ló mú kí àwọn ọlọ́pàá RRS tó wà ní láyípò náà lé wọ tí wọn si gba fóònù fún oun.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ náà agbẹnusọ fún àjọ ọlọ́pàá Chike Oti ní ọ̀rọ̀ náà rú oun lójú kí àwọn ènìyàn máa hùwà ọ̀daràn nítori pé ayẹyẹ ńbọ̀ lọ́nà.

O ní àwọn kọ̀ ní káàrẹ̀ láti rí i dájú pé Ìpínlẹ̀ Eko kìí ṣe ibi ti gbogbo àwọn ọ̀daran le dúró sí