Mo gba kádàrá lórí àìlera mi láìnáání yẹ̀yẹ́
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

2016 ni Angel kọ́kọ́ gbé àwo orin rẹ̀ jáde láti fi bèrè ìdí tí òun fi yàtọ̀

Ààbọ ara kò sọ pé kí èèyàn má dé ibi tó yẹ́ kò dé láyé ni èrò Angel Wajiri.

'Congenital Hydrocephalus' ni orúkọ àìsàn ti àwọn dókítà ni o ń ṣe Angel ni èyí ti orí rẹ̀ tóbi ju ara rẹ̀ lọ pupọ.

Angel to jẹ ọmọ ọdun merinla ṣalaye fún BBC àwọn igbesẹ ti oun n gbé láti kojú ẹ̀gàn àwọn ènìyàn lóri àìlera ara òun.

O gba àwọn akanda ẹ̀dá niyanju lati gba kadara ki wọn má jẹ ki ailera yii dènà ilọsiwaju wọn.

Angel ni oun fi àwo orin òun bèèrè ìdí tí òun fi yatọ sí àwọn ọmọ to ku.