Fayose si Buhari: Kí ló fa ìdíwọ́ àfihàn ìwé ẹ̀rí rẹ di àsìkò yí?

Buhari ati Fayose n ki ara n

Oríṣun àwòrán, @NGRPresident

Àkọlé àwòrán,

Ajọ to n ri si idanwo aṣekagba ile iwe girama, WAEC ti ṣalaye wi pe kii ṣe pe awọn ṣẹṣẹ fun Aarẹ Buhari ni iwe ẹri tuntun lọjọ ẹti

Ko si eeyan ti ko fẹrẹ mọ pe okun ifẹ laarin Aarẹ Muhammadu Buhari ati gomina ana nipinlẹ Ekiti, Peter Ayọdele Fayoṣe ko fi da bi ẹni gun rara nitori naa nigba ti wahala lori iwe ẹri aarẹ Buhari bẹrẹ, ọpọ lo reti ohun ti Fayoṣe yoo sọ lasiko naa.

Amọṣa boya nitori wahala ẹjọ lori ẹsun ṣiṣe owo ilu baṣubaṣu ti wọn fi kan an, Ayọdele ko tete sọrọ lori rẹ.

Nibayii naa, gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ naa ti jade pẹlu ibeere mẹta fun aarẹ Muhammadu lori awuyewuye iwe ẹri girama rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ninu oju opo twitter rẹ ni Fayoṣe ti beere ibeere mẹrin kan lọwọ Buhari.

"Bi o ba rọrun bayi lati ri iwe afihan pe lootọ ni o ṣe idanwo, ki lo de ti o fi pẹ bayii? Ki ni o faa ti ẹ fi du ipo ni igba mẹrin ọtọọtọ lai ni iwe ẹri kan ṣoṣo? Ti o ba ri bẹẹ, nigba wo ni awọn ologun yoo fi iwe ẹri ti aarẹ sọ pe o wa lọdọ wọn sita?

Ọpọ awọn ibeere wọnyii lo n beere fun idahun."

Eyi ni ọrọ ti Fayoṣe kọ si ori opo twitter rẹ, ṣugbọn ko daju pe ileeṣẹ aarẹ tabi aarẹ Buhari funrarẹ ṣetan lati dahun si ibeere rẹ.

Buhari ló kòwé bèrè ìwé ẹrí rẹ̀ lọ́wọ́ àjọ wa- WAEC

Oríṣun àwòrán, @WAECofficial

Àkọlé àwòrán,

WAEC: ilé ẹjọ́ àti Buhari nìkan ló le bèrè fún ìwé ẹ̀rí.

WAEC: A ò ní fún-un ní ìwé ẹ̀rí ti ààrẹ kò bá bèrè fún ìwé ẹ̀rí rẹ̀. Buhari nìkan tàbí ilé ẹjọ́ ló le bèrè fún ìwé ẹ̀rí. Kò sí ẹlòmíràn, nítorí náà ààrẹ ló bèrè fún-un.

Garba Sheu: Rárá kò kòwé bèrè ìwé ẹ̀rí. Mo sàlàyé rẹ̀ yékéyéké nínú àpilẹkọ mi lọ́jọ́ Jimọ. Àjọ WAEC kan ròó nínú ọgbọ́n inú wọn láti fún ààrẹ ní ìwé ẹrí rẹ̀ ni.

Ilé-iṣẹ́ ààrẹ àti àjọ tó ń rí sí ìdánwò àṣekágbá ní ìhà ìwọ̀-oòrùn Afirika (WAEC) ló ń ṣe gbọ́nmisíi -omi -ò -tó lóri ọ̀rọ̀ ìwé ẹ̀rí ààrẹ Muhammadu Buhari ti àjọ WAEC gbéjade lọ́jọ́ Jímọ tí kọja.

Bí ilé -iṣé ààrẹ ṣé ń sọ pé ààrẹ kò bèrè fún ìwé ẹri ìdánwò àṣekágbá rẹ̀, ní àjọ WAEC náà ń tẹnu mọ́ọ pé ààrẹ ló bèrè fún iwé ẹrí tó ní òun ṣe lọ́dún 1961.

Agbẹnusọ fún àjọ WAEC Damianus Ojijeogu ló sọ èyí ddi mímọ̀ nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan pé ti ààrẹ ò bá bèrè fún àwọn o lé kùgbùrù gbé e jáde

Àkọlé fídíò,

Omar Victor Diop: Ipa Áfíríkà nínú àkọsílẹ̀ ìwé kọja ògo tí wọ́n ń fún un lágbáyé

Ẹgbẹ́ òṣèlú APC kọ̀jálẹ̀ láti fi ìwé ẹ̀rí Buhari ṣọwọ́ sí INEC

Oríṣun àwòrán, APC

Àkọlé àwòrán,

Aarẹ Buhari ati ami idamọ APC

Ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress (APC) ti ni awọn ko ni fi iwe ri mo sedanwo ti ajọ WAEC fun aarẹ Buhari ṣọwọ si ajọ eleto idibo, INEC.

APC ni awọn ko ni fi ṣọwọ nitori ko nilo mọ. Iwe ẹri naa ni ajọ WAEC fun aarẹ lọjọ ẹti.

Alukoro ẹgbẹ naa, Lanre Isa-onilu ṣalaye pe ajọ eleto idibo ko figba kan fi lede pe oun ṣiye meji lori aridaju to lẹ mọ awọn iwe ẹri to fi ranṣẹ si ajọ naa pe ọwọ awọn ologun ni iwe ẹri idanwo aṣekagba girama wa.

O ni "a o nilo lati mu u fun ajọ INEC. INEC ko figba kan sọrọ si awọn iwe ti aar Buhari lẹ mọ awọn iwe ẹri rẹ. Nigba ti ajọ WAEC si ti fun aarẹ ni iwe ẹri rẹ, le tọ wọn lọ fun aridaju tabi alaye.

'A ò kí ǹ fún ènìyàn ní ìwé ẹ̀rí lẹ́ẹ̀méjì'

Oríṣun àwòrán, @BashirAhmaad

Àkọlé àwòrán,

Àjọ WAEC ṣàfihàn ìwé ẹ̀rí girama Ààrẹ Muhammadu Buhari

Ajọ to n ri si idanwo aṣekagba ile iwe girama, WAEC ti ṣalaye wi pe kii ṣe pe awọn ṣẹṣẹ fun Aarẹ Buhari ni iwe ẹri tuntun lọjọ ẹti.

Ajọ naa ṣalaye lori ikanni twitter rẹ pe, iwe afihan pe lootọ ni aarẹ ṣe idanwo lawọn fun un.

Ajọ WAEC ni awọn kii fun eniyan ni iwe ẹri lẹẹ meji ati pe gbogbo awọn ti iwe ẹri wọn ba sọnu pẹlu lanfani sii.

Ẹwẹ, Aarẹ Muhammadu Buhari ti ṣalaye wi pe oun ati oloogbe Shehu Musa Yaradua ni awọn jọ joko ṣe idanwo aṣekagba girama ni ọdun 1961 nitori ni asiko kan naa ni awọn darapọ mọ iṣẹ ologun.

Aarẹ Buhari ni kilaasi kan naa ni oun ati Ọgagun agba Shehu Musa Yaradua wa ni ile iwe alakọbẹrẹ ati girama ki wọn to darapọ mọ ileeṣẹ ologun.

Ni ọjọ ẹti ni aarẹ Buhari ṣalaye ọrọ yii lasiko to fi n tẹwọ gba iwe ẹri rẹ lọwọ awọn alaṣẹ ajọ eleto idanwo oniwe mẹwa, WAEC ni ile ijọba to wa nilu Abuja.

Oniruru awuyewuye lo ti n waye lori iwe ẹri girama aarẹ Buhari.

Akọwe agba ajọ WAEC, Ọmọwe iyi Uwadiae lo fun aarẹ Buhari ni iwe ẹri tuntun yii ni gbsngan ipade kekeree to wa ni ile arẹ nilu Abuja.

"Gẹgẹ bii ologun lorilẹede Naijiria, ko lee ṣeeṣe fun mi lati lọ si ileewe ẹkọṣẹ ologun ni india ni ọdun 1973 ati ile ẹkọṣẹ ologun orilẹede 1979.

Àjọ WAEC fún Buhari ní ìwé ẹ̀rí

Oríṣun àwòrán, @BashirAhmaad

Àkọlé àwòrán,

Àjọ WAEC ṣàfihàn ìwé ẹ̀rí girama Ààrẹ Muhammadu Buhari

Ẹ sinmi ariwo ni orin to da bi ẹni pe Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari n kọ bayi lẹyin ti ajọ to n ri si idanwo ile iwe girama lapa iwọ-oorun ilẹ Afirika WAEC fun un ni iwe ẹri.

Oludamọran pataki si Aarẹ Buhari, Femi Adesina lo fi ọrọ naa lede loju opo Twitter lọjọ Ẹti.

Adesina ni kin ni o tun ku ti awọn alatako Aarẹ Buhari fẹ sọ bayii, lẹyin ajọ WAEC ti safihan iwe ẹri ti wọn ni Buhari o ni.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Koda iroyin to tẹ wa lọwọ tiẹ sọ pe alakoso ajọ WAEC lo fi iwe ẹri ọhun le Aarẹ Buhari lọwọ.

Buhari ṣabẹwo si Kaduna

Aarẹ Muhammadu Buhari sọ pe ijọba apapọ orilẹede Naijiria ti ṣetan lati ṣe iwadii, ti yoo ṣi aṣọ l'oju eegun awọn aṣekupani ọhun.

Aarẹ sọrọ yii l'asiko to lọ si ipinlẹ Kaduna l'ọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii, lati ba wọn kẹdun ti awọn to kú ninu ija ẹ̀sìn to waye laipẹ yii.

Oríṣun àwòrán, @MBuhari/Twitter

Àkọlé àwòrán,

Buhari sọ pe ko si aaye fun iwadii arumọjẹ latọdọ awọn ọlọpaa lori ija ẹsin Kaduna

Buhari sọ pe ipaniyan ko bojumu rara ni Naijiria, ati pe ko si aaye fun iwadii arumọjẹ latọdọ awọn ọlọpaa lori wahala naa.

Àkọlé fídíò,

#Queen Dihya: Obinrin tó gbógun tàwọn agbésùnmọ̀mí ni Algeria

Aarẹ Buhari wa kesi Ajọ Ọlọpa lati fi gbogbo eto aabo sipo, ki alaafia le jọba ni agbeegbe naa lai doju ofin bolẹ.

Ìjà ẹ̀sìn Kaduna: Ìjọba ìpínlẹ̀ Kaduna dá kóníléógbélé padà

Iku olori ilu kan nipinlẹ Kaduna ti ṣokunfa ki ijọba fúnkùn mọ ofin konileogbele ti wọn dẹ tẹlẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lọsẹ to kọja lawọn ajinigbe gbe e salọ lẹyin iku eeyan márùndínlọ́gọ́ta ni Kasuwan Magani.

Oba Maiwada Galadima jẹ olori ẹya Adara ti wọn si lero wi pe iku rẹ le sokunfa ki ija miran tun bẹ silẹ.

Gomina ipinlẹ Kaduna Nasir El Rufai fi ikede idapada ofin konileogbele yi soju opo Twitter rẹ lọjọ ẹti.

Ni bayii, awọn olugbe Kaduna, Kasuwan Magani, Kajuru to fi mọ Kateri ati Kachia ni idapada konileogbele yi kan bayi.

Ikede naa ni konileogbele ohun bere lati ago mọkanla ọjọ ẹti tii ṣe ọjọ kerindinlọgbọn Oṣu Kewa.

Saaju ni ìgbìmọ aláṣẹ ìjọba ìpínlẹ̀ Kaduna ṣe ìpàdé kan ti igbimọ aláṣe si fẹnukò pé kí wọn mú àdínkù bá iye wákàti tí ètò kóníléógbélé yóò fi wà.

Oríṣun àwòrán, @GovKaduna

Àkọlé àwòrán,

Gomina Ipinlẹ Kaduna ati awọn olori ẹsin ti n ṣe ipade orisirisi

Abájáde ìpàdé èètò ààbò naa ti Samuel Aruwan oluranlọwọ fun Gomina Kaduna lori ọrọ ibanisọrọ fi sita ṣe àlàkalẹ ètò kóníléógbélé naa.

Sugbọn bayi ti iroyin iku Oba yi ti n ja rain-rain ijọba ti ni awọ́n yoo funkun pada mọ eto konileogbele naa lati fi dena ikọlu miran.

Oríṣun àwòrán, @GovKaduna

Lenu ọjọ mẹta yi,Gomina ipinlẹ Kaduna Ahmad El Rufai ti n ṣe ipade orisirisi pẹlu awọn olori ẹya ti ọrọ ija to bẹ silẹ yi kan.

Wahala ija to bẹ silẹ waye lẹyin ede aiyede kan to waye ninu ọja kan ni ẹkun ariwa ipinlẹ Kaduna ti o si mu ẹmi eeyan marundinlọgọta lọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bakan naa lawọn alaṣẹ ti fi ofin konile-o-gbele sita nibẹ.

Ninu ọrọ rẹ to fi sita, agbẹnusọ fun aarẹ Buhari, Garuba Shehu ni aṣa lilo rogbodiyan ati ikọlu lati yanju aawọ laarin awọn eeyan lorilẹede Naijiria ko ṣai maa kọ aarẹ orilẹede Naijiria lominu.

O ni, 'ko si aṣa tabi ẹsin to faye gba gbigba ẹmi...ibagbepọ alaafia si ṣe pataki fun idagbasoke ati igbayegbadun awujọ yoowu."

aarẹ Buhari koro oju si rogbodiyan naa pẹ̀lu afikun pe o yẹ̀ kawọ̀n aṣaaju ileto gbogbo o maa ba awọ̀n eeyan wọn sọrọ̀ lorore koore lati maa pinwọ irufẹ iṣẹlẹ bẹẹ ko to suyọ.