67 year old mother: Ìdílé Otubusin yọ ayọ̀ ọmọ lẹ́yìn ìgbéyàwó ogójì ọdún

Ìkọ́mọ
Àkọlé àwòrán,

Iya ọmọ Ajibola Otubusin ti o jẹ ẹni ọdun mẹtadinlaadọrin ko le pa idunnu rẹ mọ ra

''Njẹ ẹ ti gbọ pe Ọlọrun kii kanju?''

Ọmọ lere aye, ọmọ lasọ. Idunnu ṣubu layọ nibi ikọmọjade ọmọ tuntun ti Ọlọrun ta idile Ọjọgbon Samuel Olu Otubusin lọrẹ lẹyin ogoji odun ti wọn ṣe igbeyawo.

Iya ọmọ Ajibola Otubusin ti o jẹ ẹni ọdun mẹtadinlaadọrin ko le pa idunnu rẹ mọ ra, o sọ pe oun ko kọkọ gbagbọ pe oun loyun afi igba to de pe ọmọ bẹrẹ sii ru ninu oun ni oun to gbagbọ.

Àkọlé àwòrán,

Ojọ̀gbọ́n Samuel Otubusin

Ojogbon Samuel to je omo aadorin odun ati iyawo rẹ lasiko ti won n ba BBC Yoruba sọrọ ni ọmọ ọgọrun ọdun le di ọlọmọ ti wọn ba ti ni ipinnu to daju lai bẹru.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Àtọ̀ ọmọkùnrin ti rógo o!

Iyaafin Ajibola Otubusin salaye pe orisirisi aisan l'oun ba finra fun ọdun marundinlogoji eleyi ti ko jẹ ki oun tiẹ lero pe oun le finu ṣoyun.

Awọn tọkọ taya naa fikun wipe igbagbọ awọn to daju ati ibẹru Ọlọrun lo se koko lati duro ninu igbeyawo.

Àkọlé àwòrán,

Ojọ̀gbọ́n Samuel Otubusin