Ọọ̀ni ti Ile Ifẹ gbàlejò gómìnà ìpínlẹ̀ Anambra láàfin

Ọọ̀ni Ogunwusi àti Gómìnà Willie Obiano

Oríṣun àwòrán, Ọọ̀ni's Palace

Àkọlé àwòrán,

Ọọ̀ni Ogunwusi àti Gómìnà Willie Obiano láàfin Ọọ̀ni'rìṣà

Gómìnà Willie Obiano tai ìpínlẹ̀ Anambra ṣàbẹ̀wò sí Ilé Ifẹ láti kí Ọọ̀ni Ile Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi àti Yèyélúwà olori Ṣilẹkunla Naomi Ogunwusi kú oríire ti ìgbéyàwó wọn tó wáyé láìpẹ́.

Nígbà tó ń ṣàpèjúwe Àrólé Oduduwa, Ọọ̀ni Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi, Ọ̀jájá kejì tó tún kọ́wọ̀ọ́ jẹ́ alága ẹgbẹ́ àwọn lọ́ba lọ́ba orílẹ̀èdè Nàìjíríà, baba fún òun àti ọ̀rẹ́ ọjọ́ pípẹ́, gómìnà Obiano ní Ile Ifẹ jẹ́ ilé ìṣẹ̀mbáyé ìran Yorùba tí gbogbo ènìyàn ti ṣẹ̀ wá.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Oríṣun àwòrán, Ọọ̀ni's Palace

Àkọlé àwòrán,

Ọọ̀ni Ogunwusi àti Gómìnà Willie Obiano láàfin Ọọ̀ni'rìṣà

"Kẹ́ẹ pẹ́ Kábíyèsí, mo wà lórílẹ̀èdè Amẹ́ríkà nígbà tẹ́ẹ ṣègbéyàwó. Gẹ́gẹ́ bí ọm àti ọ̀rẹ́ yín látọjọ́ pípẹ́, mo wò ó wí pé ó ṣe pàtàkì láti láti wá kí lyin àti arẹwà Olorì Yèyélúwà níorí gbogbo ìgbà lẹ máa ń fìfẹ́ hàn sí èmi, ìyàwó mi àti ìjọba ìpínlẹ̀ wa, gbogbo ènìyàn ìpínll Anambra àti ẹ̀yà Igbo lápapọ̀".

"Kábíyèsí, mo gbàdúra fún lílọ́ra ẹ̀mí yín lórí ìtẹ́ Oduduwa, mo gbàdúrà ìlera pípé fún ẹ̀yin àti ìyàwó yín Yèyélúwà. Ọlọ́run yóò bùkún ìgbéyàwó yín pẹ̀lú ọmọ rere.

Àkọlé fídíò,

Àtọ̀ ọmọkùnrin ti rógo o!

Oríṣun àwòrán, Ọọ̀ni's Palace

Àkọlé àwòrán,

Yeyeluwa Naomi Ogunwusi àti Gómìnà Willie Obiano láàfin Ọọ̀ni'rìṣà

Ní ìdáhùn, Àrólé Oduduwa dúpẹ́ lọ́wọ́ Gómìnà Obiano fún àbẹ̀wò rẹ̀, òun náà ṣàpèjúwe rl gẹ́gẹ́ bí bí ọ̀rẹ̀ ọjọ́ pípẹ́ tó máa ń fi gbogbo ìgbà fìfẹ́ àti ìbọ̀wọ̀ hàn fún ìtẹ́ Oduduwa àti àpapọ̀ ẹgbẹ́ lọ́ba lọ́ba Nàìjíríà.

Oríṣun àwòrán, Ọọ̀ni's Palace

Àkọlé àwòrán,

Ọọ̀ni Ogunwusi àti Gómìnà Willie Obiano láàfin Ọọ̀ni'rìṣà

Àkọlé fídíò,

Ooni: Mo ti fi ọ̀rọ̀ obinrin tó ń parọ́ ìfẹ́ mọ́ mi sun agbófinró