#67yearoldmother: Mo kojú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àìsàn fún ọdún 35 lẹ̀yín ìgbéyàwò

#67yearoldmother: Mo kojú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àìsàn fún ọdún 35 lẹ̀yín ìgbéyàwò

Ìyá ọmọ tuntun: aṣiwèrè ló máa sọ pé Ọlọrun kò sí, Ìyanu ni ọmọ ti mo bí yìí.

Ajibola Otubusin, ti o jẹ ẹni ọdun mẹtadinlaadọrin to tun ṣẹsẹ di ìyá ọmọ tuntun jòjòló ti ni ko si ohun to ṣoro fun Ọlọrun lati ṣe ti eniyan ba ni igbagbọ ati ifọkansin.

Abilekọ Otubusin sọ eyi lasiko ti ó n ba BBC Yoruba sọrọ lasiko ti ìkómọjade ọmọ tuntun ti Oluwa fi jíǹkí rẹ̀ lẹyin igbeyawo fun ogoji ọdun lai bimọ n waye nilu Abẹokuta, nipinlẹ Ogun.

Ọjọgbọn Otubusin to jẹ baba ìkókó naa jẹ ọmọ aadọrin ọdún. Oun naa ṣalaye fun BBC Yorùbá pé ọwọ́ Oluwa ni gbogbo ẹ̀yà ara ẹ̀dá wà ati pe kò sí ohun ti Ọlọrun kò le ṣe.

Iya Otubusin fikun wi pe oun paapaa ko kọkọ gbagbọ nigba ti ayẹwo fihan pe oun ti loyun, yàtọ̀ sí ọpọlọpọ ipenija ti òun ti kojú ninu ìlera ara oun lati ọdun marundinlogoji sẹyin. O tun sọrọ lori iṣorọ ti oun koju lasiko iloyun fun oṣù mẹsan.

Tọkọtaya Otubusin wa fi gbogbo ogo fun Ọlọrun wi pe oun lo ṣe ohun iyanu yii fun wọn.

Ojogbon Samuel to je omo aadorin odun ati iyawo rẹ ni ọmọ ọgọrun ọdun le di ọlọmọ ti wọn ba ti ni ipinnu to daju lai bẹru pẹlu igbagbọ ninu Ọlọrun alaaye.

Ijọ Anglican ni wọn ti ṣe igbeyawo lọdun 1977 nigba ti wọn ṣe ètò IVF naa nile iwosan kan nipinle Eko.

Iya ọmọ tuntun naa ṣalaye fun BBC pe oriṣiiriṣii aisan lo ṣe ẹ̀dọ̀, kidinrin àti ọ̀fun oun yatọ si oyún ìju, ṣugbọn oun bori gbogbo rẹ nigbẹyin ti wọn a si maa fi orukọ ọmọ pe oun naa bayii.

Ọpọlọpọ awọn eniyan lo bá wọn dunnú ti orukọ ọmọkunrin jòjòló naa pọ loriṣiiriṣii.