#Adetutu Alabi OJ: Mo ti gba kámú lórí ilà ojú mi

#Adetutu Alabi OJ: Mo ti gba kámú lórí ilà ojú mi

'Àwọn aladugbo ati akẹgbẹ́ mi nile ìwé ti fún mi ni ọpọlọpọ ìṣoro sẹyin lori ilà ti mo kọ'.

Ilà kíkọ jẹ́ ọ̀kan lára àmì idanimọ ìran Yorùbá. Laye atijọ wọ́n maa n fi ilà kikọ da idile, ìlú àti ẹ̀yà èèyàn mọ, bi apẹẹrẹ, o ni irúfẹ́ ilà ti àwọn ọmọ Ọba alade ẹ̀yà kan máa n kọ.

Laye ode oni, àṣà ilà kikọ ti n dinku lawujọ nitori pé àwọn eeyan miran maa n dẹ́yẹ si àwọn ọ̀kọlà nitori ọ̀làjú.

Arinrin oge, Adetutu Alabi OJ ṣalaye fun BBC nipa àwọn iriri rẹ lori ilà ti wọn kọ fun un yii.

O mẹnuba awọn nkan to ti padanu sẹyin ati bi oun ṣe ti ni igboya tuntun lori ila oju oun nisinsinyi.

Adetutu ni ìmọ̀ oun ti kún sii pé, ẹni to ba maa nifẹ oun kò ni naani ilà oju oun nitori pe Ilà oun yatọ si irú ẹni ti oun jẹ́.

Agbẹnusọ fawọn ọ̀kọlà lawujọ yii gba awọn eeyan nimọran pe ki wọn dẹkun fifi ọ̀kọlà ṣe yẹ̀yẹ́ nitori ìwà abùkù ni.